Yorùbá
Àlàyé Nípa Òwe 3:5, 6—‘Má Tẹ̀ Lé Ìmọ̀ Ara Rẹ’
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/502300100/univ/art/502300100_univ_sqr_xl.jpg
ijwbv àpilẹ̀kọ 14

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Òwe 3:5, 6—‘Má Tẹ̀ Lé Ìmọ̀ Ara Rẹ’

Òwe 3:5, 6—‘Má Tẹ̀ Lé Ìmọ̀ Ara Rẹ’

 “Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ, á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA, má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ. Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ, yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6, Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

Ìtumọ̀ Òwe 3:5, 6

 Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, dípò ká kàn ṣe ohun tó wù wá, ṣe ló yẹ ká wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà a Ọlọ́run.

 “Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” Tá a bá ń ṣe nǹkan lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́, ìyẹn fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e. Ó yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” láti sọ irú ẹni tẹ́nì kan jẹ́ gangan, ìyẹn bí nǹkan ṣe máa ń rí lára ẹ̀, ohun tó ń mú un ṣe nǹkan, ohun tó ń rò àti ìwà ẹ̀. Torí náà, èèyàn ò kàn lè dédé gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run torí ó kàn rò pé ó yẹ kóun ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣe lèèyàn máa ń dìídì pinnu láti gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run torí ó dá onítọ̀hún lójú pé òun ni Ẹlẹ́dàá ó sì mọ ohun tó dáa jù fún wa.—Róòmù 12:1.

 ‘Má gbára lé òye tìrẹ.’ Torí pé aláìpé ni wá, a ò lè gbára lé òye tara wa. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Tó bá jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lára wa la fi ń pinnu ohun tá à ń ṣe, a lè ṣe àwọn ìpinnu kan táá kọ́kọ́ dà bíi pé ó dáa àmọ́ tó wá pa dà yọrí síbi tí kò dáa. (Òwe 14:12; Jeremáyà 17:9) Ọgbọ́n Ọlọ́run ju tiwa lọ fíìfíì. (Àìsáyà 55:8, 9) Tá a bá ń jẹ́ kí Ọlọ́run tọ́ wa sọ́nà, ayé wa á nítumọ̀.—Sáàmù 1:1-3; Òwe 2:6-9; 16:20.

 “Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ.” Tá a bá fẹ́ ṣe ohunkóhun nígbèésí ayé wa tàbí tá a fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì kan, ó yẹ ká máa ronú nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ká ṣe. Ìyẹn sì gba pé ká máa gbàdúrà sí i pé kó tọ́ wa sọ́nà, bákan náà, ká máa ṣe ohun tí Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá sọ.—Sáàmù 25:4; 2 Tímótì 3:16, 17.

 ‘Á mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ.’ Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń mú ọ̀nà wa tọ́? Ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. (Òwe 11:5) Ìyẹn ló ń jẹ́ káyé wa ládùn, kó sì lóyin, tí kì í sì í jẹ́ ká fọ́wọ́ ara wa fa ìṣòro.—Sáàmù 19:7, 8; Àìsáyà 48:17, 18.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé Òwe 3:5, 6

 Ìwé Òwe jẹ́ ká mọ àwọn ohun pàtàkì tó yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ káyé wa nítumọ̀ kó sì múnú Ọlọ́run dùn. Ọ̀rọ̀ ìnú orí mẹ́sàn-án àkọ́kọ́ dà bí ìgbà tí bàbá ń fún ọmọ ẹ̀ tó nífẹ̀ẹ́ nímọ́ràn. Orí kẹta sọ àǹfààní téèyàn máa rí tó bá ń fi ọgbọ́n Ọlọ́run sílò.—Òwe 3:13-26.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.