OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Kí Ni Bábílónì Ńlá?

Yorùbá
Kí Ni Bábílónì Ńlá?
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/502015210/univ/art/502015210_univ_sqr_xl.jpg
ijwbq àpilẹ̀kọ 94

Kí Ni Bábílónì Ńlá?

Kí Ni Bábílónì Ńlá?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ìwé Ìfihàn sọ̀rọ̀ nípa “obìnrin” kan tó jẹ́ “aṣẹ́wó ńlá,” tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ “ohun ìjìnlẹ̀ kan: ‘Bábílónì Ńlá.’ ” (Ìfihàn 17:1, 3, 5) Obìnrin yìí ṣàpẹẹrẹ àgbájọ gbogbo ẹ̀sìn èké tó wà láyé, àwọn ẹ̀sìn tó ti “fi irọ́ pààrọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.” a (Róòmù 1:25) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀sìn yìí yàtọ̀ síra lóríṣiríṣi ọ̀nà, gbogbo wọn ló ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, kí wọ́n má bàa jọ́sìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́.—Diutarónómì 4:35.

Àwọn ohun tá a lè fi dá Bábílónì Ńlá mọ̀

  1.   Àmì ni Bábílónì Ńlá jẹ́. Torí pé “àmì” làwọn ohun tó wà nínú ìwé Ìfihàn, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Bábílónì Ńlá kì í ṣe obìnrin gidi, àmì ló jẹ́. (Ìfihàn 1:1) Bákan náà, ó “jókòó lórí omi púpọ̀,” èyí tó ṣàpẹẹrẹ “àwọn èèyàn àti èrò rẹpẹtẹ àti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ahọ́n.” (Ìfihàn 17:1, 15) Èèyàn ẹlẹ́ran ara ò lè ṣe ohun tí Bíbélì sọ yìí.

  2.   Bábílónì Ńlá ṣàpẹẹrẹ ètò kan tó nasẹ̀ dé orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Bíbélì pè é ní “ìlú ńlá títóbi tí ó ní ìjọba kan lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” (Ìfihàn 17:18) Torí náà, kárí ayé ni ẹsẹ̀ rẹ̀ ti tólẹ̀.

  3.   Ètò ìsìn ni Bábílónì Ńlá, kì í ṣe ètò òṣèlú tàbí ọrọ̀ ajé. Ìlú Bábílónì ayé àtijọ́ gbóná tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, ìlú tí wọ́n ti ń fi “èèdì” di àwọn èèyàn, tí wọ́n sì ti ń ṣe “iṣẹ́ àjẹ́” làwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí. (Àìsáyà 47:1, 12, 13; Jeremáyà 50:1, 2, 38) Kódà, Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ kọ́ ni wọ́n ń jọ́sìn níbẹ̀, ẹ̀sìn èké ni wọ́n ń ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 10:8, 9; 11:2-4, 8) Agbéraga làwọn tó ń ṣàkóso ní Bábílónì, wọn ò sì ka Jèhófà àti ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn rẹ̀ sí nǹkan kan. (Àìsáyà 14:4, 13, 14; Dáníẹ́lì 5:2-4, 23) Bákan náà, àwọn èèyàn tún mọ Bábílónì Ńlá sí ‘abẹ́mìílò.’ Ìyẹn ló fi hàn lóòótọ́ pé ètò ẹ̀sìn ni.—Ìfihàn 18:23.

     Bábílónì Ńlá ò lè jẹ́ ètò ìṣèlú, torí pé “àwọn ọba ayé” máa ṣọ̀fọ̀ nígbà tó bá pa run. (Ìfihàn 17:1, 2; 18:9) Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ètò ọrọ̀ ajé, torí ohun tí Bíbélì sọ fi hàn pé ó yàtọ̀ sí “àwọn oníṣòwò ayé.”—Ìfihàn 18:11, 15.

  4. Fọ́tò yìí jẹ́ nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda British Museum

    Òkúta tí wọ́n gbẹ́ àwòrán Ọba Nábónídọ́sì ilẹ̀ Bábílónì sí, pẹ̀lú àwòrán òrìṣà Sin, Ishtar àti Shamash tó para pọ̀ jẹ́ ọlọ́run mẹ́talọ́kan

  5.   Àpèjúwe tí Bíbélì ṣe nípa ẹ̀sìn èké bá Bábílónì Ńlá mu. Ṣe ni ẹ̀sìn èké ń mú káwọn èèyàn máa jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì dípò kó máa kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́. Bíbélì pe ohun tí wọ́n ń ṣe yìí ní “àgbèrè” ẹ̀sìn. (Léfítíkù 20:6, Bíbélì Mímọ́; Ẹ́kísódù 34:15, 16) Ìlú Bábílónì ayé àtijọ́ ni àwọn ẹ̀kọ́ bíi Mẹ́talọ́kan àti àìleèkú ọkàn ti wá, títí kan àṣà fífi ère jọ́sìn. Àwọn àṣà àti ẹ̀kọ́ yẹn ò kúrò nínú ẹ̀sìn èké títí dòní. Àwọn ẹ̀sìn yìí tún ń ṣèyí-ṣọ̀hún, wọ́n láwọn ń jọ́sìn, wọ́n tún ń nífẹ̀ẹ́ ayé. Ìwà àìṣòótọ́ nìyẹn, Bíbélì sì fi wọ́n wé alágbèrè.—Jémíìsì 4:4.

     Bíbélì fi Bábílónì Ńlá wé obìnrin tó wọ “aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aláwọ̀ pọ́pù,” wọ́n sì “fi wúrà, àwọn òkúta iyebíye àti péálì ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.” Àfiwé yìí bá ìsìn èké mu torí ó lọ́rọ̀, ó sì fi ń yangàn. (Ìfihàn 17:4) Bábílónì Ńlá ni orísun “àwọn ohun ìríra ayé” tàbí àwọn ẹ̀kọ́ àti ìwà tí inú Ọlọ́run ò dùn sí. (Ìfihàn 17:5) Àwọn tó wà nínú ẹ̀sìn èké ni “àwọn èèyàn àti èrò rẹpẹtẹ àti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ahọ́n” tó ń ti Bábílónì Ńlá lẹ́yìn.—Ìfihàn 17:15.

 Bábílónì Ńlá ló fa ikú “gbogbo àwọn tí wọ́n pa ní ayé.” (Ìfihàn 18:24) Ọjọ́ pẹ́ tí ẹ̀sìn èké ti ń rúná sí ogun, tí wọ́n sì ń kọ́wọ́ ti àwọn apániláyà, bẹ́ẹ̀ ni wọn ò fi òtítọ́ nípa Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́ kọ́ àwọn èèyàn. (1 Jòhánù 4:8) Ohun tí wọ́n ṣe yìí ti mú kí wọ́n fi ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ṣòfò.

Báwo ni àwọn ohun tí Bábílónì Ńlá ń ṣe ṣe rí lára Ọlọ́run?

 Lójú Ọlọ́run, “àwọn ẹ̀ṣẹ̀ [Bábílónì Ńlá] ti ga dé ọ̀run.” (Ìfihàn 18:4, 5) Inú ń bí Ọlọ́run sí ẹ̀sìn èké torí pé wọn ò kọ́ àwọn èèyàn ní òótọ́ nípa Ọlọ́run, wọ́n sì ń hùwà àìdáa sáwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn.

Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Bábílónì Ńlá?

 Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run ti kéde ìdájọ́” sórí Bábílónì Ńlá. (Ìfihàn 18:20) Ohun tí Bíbélì ń sọ ni pé Ọlọ́run máa pa gbogbo ẹ̀sìn èké run. (Ìfihàn 18:8) Ó máa mú kí ẹranko aláwọ̀ rírẹ̀dòdò kan, tó ṣàpẹẹrẹ ètò òṣèlú kan tó lágbára, kẹ̀yìn sí ẹ̀sìn èké, á sì pa á run pátápátá. (Ìfihàn 17:16, 17) “Báyìí la ṣe máa yára ju Bábílónì ìlú ńlá náà sísàlẹ̀, a ò sì ní rí i mọ́ láé.” (Ìfihàn 18:21) Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kí àwọn tó fẹ́ máa ṣe ohun tínú Ọlọ́run dùn sí rí i dájú pé àwọn “jáde kúrò láàárín wọn,” kí wọ́n má sì ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn èké.—2 Kọ́ríńtì 6:14-17.

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?