Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Ní Ìdílé Aláyọ̀?

Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Ní Ìdílé Aláyọ̀?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bẹ́ẹ̀ ni. Díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n láti inú Bíbélì tó ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin lọ́wọ́ láti ní ìdílé aláyọ̀ nìyí:

  1.   Ẹ ṣe ìgbéyàwó lọ́nà tó bá òfin mu. Bí ìdílé bá máa láyọ̀, kí tọ̀túntòsì sì fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe wọn, ó ṣe pàtàkì pé kí ọkùnrin àti obìnrin ṣe ìgbéyàwó lọ́nà tó bá òfin mu.​—Mátíù 19:4-6.

  2.   Ẹ ní ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀. Bí o bá ṣe fẹ́ kí ọkọ tàbí aya rẹ máa ṣe sí ọ ni kí ìwọ náà máa ṣe sí i.​—Mátíù 7:12; Éfésù 5:25, 33.

  3.   Ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ tí kò dáa. Ọ̀rọ̀ tó dára ni kí o máa sọ kódà tí ọkọ tàbí aya rẹ bá sọ ohun tó dùn ọ́ tàbí tó ṣe ohun tó dùn ọ́. (Éfésù 4:31, 32) Bíbélì sọ ní Òwe 15:1 pé: “Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.”

  4.   Ẹ jẹ́ olóòótọ́ sí ara yín. Ẹni tó jẹ́ ọkọ tàbí aya rẹ nìkan ni kí ìfẹ́ rẹ máa fà sí, òun nìkan sì ni kí ẹ jọ máa ní ìbálòpọ̀. (Mátíù 5:28) Bíbélì sọ pé: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí ibùsùn ìgbéyàwó sì wà láìní ẹ̀gbin.”​—Hébérù 13:4.

  5.   Ẹ máa kọ́ àwọn ọmọ yín tìfẹ́tìfẹ́. Ẹ má ṣe gbàgbàkugbà fún ọmọ yín, ẹ má sì ṣe lé koko mọ́ ọn.​—Òwe 29:15; Kólósè 3:21.