OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ìgbà wo ni òpin ayé máa dé?

Yorùbá
Ìgbà wo ni òpin ayé máa dé?
https://cms-imgp.jw-cdn.org/img/p/502016161/univ/art/502016161_univ_sqr_xl.jpg
ijwbq àpilẹ̀kọ 109

Ìgbà Wo Ni Òpin Ayé Máa Dé?

Ìgbà Wo Ni Òpin Ayé Máa Dé?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Láti mọ ìgbà tí òpin ayé máa dé, ó yẹ ká mọ ohun tí ọ̀rọ̀ náà “ayé” tó wà nínú Bíbélì máa ń túmọ̀ sí. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, koʹsmos, tó túmọ̀ sí “ayé,” sábà máa ń tọ́ka sí aráyé, pàápàá àwọn tó kẹ̀yìn sí Ọlọ́run, tí wọn ò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Jòhánù 15:18, 19; 2 Pétérù 2:5) Nígbà míì, koʹsmos máa ń tọ́ka sí ètò ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn.​—1 Kọ́ríńtì 7:31; 1 Jòhánù 2:15, 16. a

Kí ni “òpin ayé”?

 Ọ̀pọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà, “òpin ayé,” a sì tún lè pè é ní “ìparí ètò àwọn nǹkan” tàbí “ìparí igbeaye yìí.” (Mátíù 24:3; Bibeli Yoruba Atọ́ka) Kì í ṣe ìparun ayé tàbí gbogbo aráyé ló ń tọ́ka sí, òpin ètò ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn ló ń tọ́ka sí.​—1 Jòhánù 2:17.

 Bíbélì fi kọ́ni pé “àwọn aṣebi ni a óò ké kúrò” kí àwọn èèyàn rere lè máa gbádùn lórí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:9-​11) Ìparun yìí máa wáyé nígbà “ìpọ́njú ńlá,” èyí tó máa yọrí sí ogun Amágẹ́dọ́nì.​—Mátíù 24:21, 22; Ìṣípayá 16:14, 16.

Ìgbà wo ni òpin ayé máa dé?

 Jésù sọ pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36, 42) Ó tún sọ pé òjijì ni òpin máa dé, “ní wákàtí tí ẹ kò ronú pé yóò jẹ́.”​—Mátíù 24:44.

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè mọ ọjọ́ àti wákàtí náà gan-an, Jésù jẹ́ ká mọ “àmì” tàbí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, tó máa jẹ́ ká mọ àwọn ohun tó máa wáyé kí òpin ayé tó dé. (Mátíù 24:3, 7-​14) Bíbélì pé àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà máa wáyé ní “àkókò òpin,” “ìgbà ìkẹyìn,” àti “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”​—Dáníẹ́lì 12:4; Bíbélì Mímọ́; 2 Tímótì 3:1-5.

Ṣé ohunkóhun máa ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí òpin ayé bá dé?

 Bẹ́ẹ̀ ni. Ayé tá à ń gbé yìí ò ní pa run, torí Bíbélì sọ pé “kò lè ṣípò padà láéláé.” (Sáàmù 104:5, Bíbélì Mímọ́) Àwọn èèyàn á sì kún ayé, bí ìlérí tó wà nínú Bíbélì, tó ní: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Ọlọ́run máa wá ṣe àwọn ohun tó ti ní lọ́kàn láti ṣe:

a Àwọn Bíbélì kan tún túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, ai·onʹ sí “ayé”. Tí wọ́n bá túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí, ìtumọ̀ ai·onʹ àti koʹsmos máa ń jọra, òun náà máa ń tọ́ka sí ètò ìgbésí ayé ẹ̀dá èèyàn.