OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ
Òpin Ayé
Ìwé 1 Jòhánù 2:17 sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.” “Ayé” wo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ? Báwo ló ṣe máa kọjá lọ, ìgbà wo ló sì máa jẹ́?
“Ayé” wo ló máa pa run?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Ayé tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ń hu àwọn ìwà tí inú Ọlọ́run kò dùn sí, èyí fi hàn pé kì í ṣe ayé tá a wà nínú rẹ̀ yìí ló máa pa run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ayé náà dúró fún àwọn èèyàn burúkú tí kò ka Ọlọ́run sí, tí wọ́n sì sọ ara wọn di ọ̀tá Ọlọ́run. (Jákọ́bù 4:4) Àwọn èèyàn tó para pọ̀ di ayé tí à ń wí yìí máa “fara gba ìyà ìdájọ́ ìparun àìnípẹ̀kun.” (2 Tẹsalóníkà 1:7-9) Ní ìdàkejì, àwọn èèyàn tó ń tẹ̀ lé àṣẹ Jésù Kristi láti má ṣe jẹ́ “apá kan ayé” máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 15:19.
Kódà, 1 Jòhánù 2:17 parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” Bó ṣe jẹ́ gan-an nìyẹn, wọ́n máa gbádùn ìwàláàyè títí láé níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Ìwé Sáàmù 37:29 sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”
“Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀.”—1 Jòhánù 2:15.
Báwo ni ayé ṣe máa pa run?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Ọ̀nà méjì ni òpin ayé máa gbà wá. Àkọ́kọ́, Ọlọ́run máa pa gbogbo ìsìn èké run, ìyẹn “Bábílónì Ńlá” tí Bíbélì ṣàpèjúwe rẹ̀ pé ó jẹ́ aṣẹ́wó. (Ìṣípayá 17:1-5; 18:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní ti Ọlọ́run làwọn ń ṣe, síbẹ̀ wọ́n ń ṣagbátẹrù àwọn ìjọba ayé. Àmọ́ tó bá yá, àwọn ìjọba náà máa kẹ̀yìn sí wọn. Bíbélì sọ pé: “[Wọn] yóò kórìíra aṣẹ́wó náà, wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparundahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán, wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.”—Ìṣípayá 17:16.
Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run máa dojú ìjà kọ àwọn aláṣẹ, ìyẹn “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá.” Ọlọ́run máa pa wọ́n run papọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹni ibi nígbà “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” tá a tún ń pè ní “Ha-Mágẹ́dọ́nì.”—Ìṣípayá 16:14, 16.
“Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé . . . Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù. Bóyá a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Jèhófà.”—Sefanáyà 2:3.
Ìgbà wo ni ayé máa pa run?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
Òpin ayé máa dé lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn bá gbọ́ ìwàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, ìyẹn ìṣàkóso tó máa rọ́pò ìjọba àwọn èèyàn. (Dáníẹ́lì 7:13, 14) Jésù Kristi sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run jẹ́ onídàájọ́ òdodo àti aláàánú, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn “àmì” tó fi hàn pé òpin ayé kò ní pẹ́ dé. Àwọn àmì míì ni ogun tó kárí ayé, ìmìtìtì ilẹ̀, àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn.—Mátíù 24:3; Lúùkù 21:10, 11.
Bíbélì tún sọ nǹkan míì tó máa jẹ́ àmì “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ìyẹn ni bí ìwàkiwà ṣe máa gbòde kan. Bíbélì sọ pé: “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . aṣàìgbọràn sí òbí, . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” *—2 Tímótì 3:1-5.
Ayé, ìyẹn àwọn èèyàn burúkú máa tó “kọjá lọ.”—1 Jòhánù 2:17
Gbogbo àwọn àmì yìí bẹ̀rẹ̀ sí í fara hàn látìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní, tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Bákan náà, láti ọdún yẹn la ti ń polongo Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì kà á sí ohun iyì pé àwọn èèyàn mọ̀ wá mọ iṣẹ́ ìwàásù yìí. Kódà, àkọlé ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwé tí à ń fún àwọn èèyàn ni Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà.
“Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí náà.”—Mátíù 25:13.
^ ìpínrọ̀ 14 Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo orí 9 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ó tún wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo.