Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ẹranko Ńlá Tí Wọ́n Ń Pè Ní Dinosaur?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ẹranko Ńlá Tí Wọ́n Ń Pè Ní Dinosaur?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì ò sọ̀rọ̀ nípa ẹranko yìí ní tààràtà. Àmọ́ Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ló “dá ohun gbogbo,” torí náà, ó ṣe kedere pé ẹranko yìí wà lára àwọn ohun tí Ọlọ́run dá. a (Ìṣípayá 4:11) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò dárúkọ ẹranko yìí, ó tọ́ka sí àwọn ẹranko kan tá a lè gbà pé dinosaur wà lára rẹ̀:

Ṣé ara àwọn ẹranko míì ni àwọn dinosaur ti jáde?

 Àwọn àṣẹ́kù tí àwọn awalẹ̀pìtàn rí jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé àwọn ẹranko yìí ń fara hàn díẹ̀díẹ̀, bí ìgbà tá a bá sọ pé ẹranko míì ló ń para dà dì wọ́n. Èyí bá ohun tí Bíbélì sọ mú pé Ọlọ́run ló dá gbogbo ẹranko. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 146:6 pe Ọlọ́run ní “Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, òkun, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn.”

Ìgbà wo ni àwọn dinosaur gbé láyé?

 Bíbélì sọ pé ọjọ́ karùn-ún àti ìkẹfà tí Ọlọ́run dá àwọn nǹkan ló dá àwọn ẹran inú òkun àtàwọn ẹran orí ilẹ̀. b (Jẹ́nẹ́sísì 1:20-​25, 31) Torí náà, ohun tí Bíbélì sọ fi hàn pé àwọn dinosaur gbé ayé pẹ́.

Ṣé dinosaur ni Béhémótì àti Léfíátánì?

 Rárá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé irú ẹranko báyìí ni Béhémótì àti Léfíátánì tí ìwé Jóòbù sọ̀rọ̀ wọn, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé erinmi ni Béhémótì, wọ́n sì gbà pé ọ̀ọ̀nì ni Léfíátánì. Bí Bíbélì sì ṣe ṣàlàyé wọn jẹ́ ká gbà pé òótọ́ ni. (Jóòbù 40:15-​23; 41:1, 14-​17, 31) Èyí ó wù kó jẹ́, “Béhémótì” àti “Léfíátánì” kì í ṣe dinosaur. Ọlọ́run sọ fún Jóòbù pé kí òun fúnra rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ẹranko yìí, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí kò sí dinosaur kankan mọ́ láyé ni Jóòbù sì gbé láyé.​—Jóòbù 40:16; 41:8.

Kí ló ṣẹlẹ̀ sí àwọn dinosaur?

 Bíbélì ò sọ nǹkan kan nípa bá ò ṣe rí àwọn dinosaur mọ́. Àmọ́ ó sọ pé “torí ìfẹ́ [Ọlọ́run]” la ṣe dá ohun gbogbo, torí náà, ó ṣe kedere pé ó nídìí tí Ọlọ́run fi dá àwọn dinosaur. (Ìṣípayá 4:11) Nígbà tí ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn sì ṣẹ, ó fàyè gbà á kí ìran àwọn dinosaur tán láyé.

a Àwọn àṣẹ́kù egungun táwọn awalẹ̀pìtàn rí jẹ́ ká gbà pé ẹranko yìí ti fìgbà kan wà. Kódà, àwọn àṣẹ́kù yẹn jẹ́ ká rí i pé ìgbà kan wà tí àwọn ẹranko yìí pọ̀ lóríṣiríṣi, àti kékeré àti ńlá.

b Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ọjọ́” lè tọ́ka sí àsìkò tó gùn tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:31; 2:1-4; Hébérù 4:4, 11.