Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Moore

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Moore

 Ìwádìí fi hàn pé àwọn èèyàn tó bá ń moore máa ń láyọ̀, wọ́n máa ń ní ìlera tó dáa, ó máa ń rọrùn fún wọn láti kojú ìṣòro, wọ́n sì máa ń ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Olùṣèwádìí kan tó ń jẹ́ Robert A. Emmons sọ pé ẹni tó bá moore “kì í ṣe ìlara, kì í ìbínú, kì í lójú kòkòrò àti kì í sì dììyàn sínú.” a

 Bí àwọn ọmọ bá lẹ́mìí ìmoore, báwo lo ṣe máa ṣe wọ́n láǹfààní? Ìwádìí kan tí wọ́n fi ọdún mẹ́rin ṣe nípa àwọn ọ̀dọ́ tí iye wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje (700) fi hàn pé àwọn tó moore lára àwọn ọ̀dọ́ náà ò fi bẹ́ẹ̀ jíwèé wò nígbà ìdánwò, wọn ò mutí, wọn ò lo oògùn olóró, wọn ò sì hùwà tí kò tọ́.

 •   Ẹní bá ń rò pé òun lẹ́tọ̀ọ́ sí gbogbo nǹkan kì í moore. Ọ̀pọ̀ ọmọdé máa ń rò pé ẹ̀tọ́ àwọn ni gbogbo ohun rere tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn. Ẹni bá ń ronú pé ṣe làwọn tó ń ṣe òun lóore jẹ òun ní gbèsè irú oore bẹ́ẹ̀, máa ń ya abaramóorejẹ.

   Irú èrò bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ lóde òní. Ìyá kan tó ń jẹ́ Katherine sọ pé: “Ohun tí ayé yìí fi ń kọ́ni ni pé gbogbo nǹkan lèèyàn lẹ́tọ̀ọ́ sí. Ìwé ìròyìn, tẹlifíṣọ̀n àti Íńtánẹ́ẹ̀tì ń fi ọ̀pọ̀ nǹkan tó yẹ ká gbà pé a lẹ́tọ̀ọ́ sì hàn wá, ó sì ń sọ fún wa pé àwa ló yẹ ká kọ́kọ́ ní wọn.”

 •   Ọmọdé lè kọ́ béèyàn ṣe ń moore láti kékeré. Ìyá kan tó ń jẹ́ Kaye sọ pé: “Àwọn ọmọdé dùn ún kọ́. Wọ́n kúkú sọ pé àtikékeré la ti ń pẹ̀ka ìrókò, torí náà àtikékeré ló yẹ ká ti fi ìwà rere kọ́ wọn àwọn ọmọdé.”

Bí òbí ṣe lè kọ́ ọmọ láti máa moore

 •   Kọ́ wọn ni ohun tí wọ́n á sọ. Àwọn ọmọdé pàápàá lè kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ káwọn máa dúpẹ́ bí ẹnì kan bá fún wọn lẹ́bùn tàbí tó ṣe wọ́n lóore. Bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà tí wọ́n sì ń gbọ́n sí i, wọ́n á túbọ̀ máa mọrírì ohun táwọn míì bá ṣe fún wọn.

   Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa dúpẹ́.”—Kólósè 3:15.

   “Ọmọ-ọmọ wa tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ta máa ń tètè sọ pé ‘ẹ ṣeun,’ tó bá sì fẹ́ béèrè fún nǹkan á kọ́kọ́ sọ pé ‘ẹ jọ̀wọ́.’ Ohun táwọn òbí rẹ̀ fi kọ́ ọ nìyẹn. Ìwà tí wọ́n ń hù àti bó ṣe gbọ́ tí wọ́n máa ń dúpẹ́ ló sọ òun náà di ẹni tó mọpẹ́ẹ́dá.”—Jeffrey.

 •   Kọ́ wọn ní òun tí wọ́n á ṣe. O ò ṣe ní káwọn ọmọ rẹ kọ̀wé ìdúpẹ́ nígbà míì tí ẹnì kan bá fún wọn ní ẹ̀bùn kan? Tó o bá tún ń fún àwọn ọmọ rẹ̀ níṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ṣe nínú ilé, wàá jẹ́ kí wọ́n mọrírì bó ṣe gba ìsapá tó láti mú kí nǹkan máa lọ geerege nínú ìdílé.

   Ìlànà Bíbélì: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

   “Àwọn ọmọ wa méjèèjì tí ò tíì pé ogún ọdún máa ń ṣe ipa tiwọn nínú ilé. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń se oúnjẹ, wọ́n sì máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ ilé pẹ́ẹ́ẹ̀ẹ̀pẹ́. Ìyẹn jẹ́ kí wọ́n mọrírì ìsapá àwa òbí wọn, wọ́n sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wa.”—Beverly.

 •   Kọ́ wọn ní ìwà tí wọ́n á hù. Bí ilẹ̀ tó dáa ṣe máa ń mú kí irúgbìn hù dáadáa, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ìrẹ̀lẹ̀ ṣe máa ń mú kéèyàn mọpẹ́ẹ́dá. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ máa ń gbà pé àwọn nílò ìrànlọ́wọ́ ẹlòmíì káwọn tó lè ṣe ohunkóhun láṣeyọrí, ìyẹn sì máa ń mú kí wọ́n dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó bá ràn wọ́n lọ́wọ́.

   Ìlànà Bíbélì: “Ẹ jẹ́ kí ìrẹ̀lẹ̀ máa mú kí ẹ gbà pé àwọn míì sàn jù yín lọ, bí ẹ ṣe ń wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.”—Fílípì 2:3, 4.

   “Nígbà míì tá a bá ń jẹ́un, a máa ń ṣeré tó ń rán wa létí pé ká máa dúpẹ́. Olúkúlùkù wa máa ń sọ ohun tó dúpẹ́ fún. Eré náà máa ń jẹ́ kí gbogbo wa ní èrò tó dáa, èrò tó fẹ́mì ìmoore hàn dípò ká máa ro èròkerò, tàbí ká mọ tara wa nìkan.”—Tamara.

 Ìmọ̀ràn kan rèé: Fi àpẹẹrẹ lélẹ̀. Ó máa rọrún fáwọn ọmọ láti máa dúpẹ́ tí wọ́n bá gbọ́ tó ò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn míì, tó o sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn náà.

a Látinú ìwé Thanks! How Practicing Gratitude Can Make You Happier.