Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrànlọ́wọ́ Fún Ìdílé | Ọmọ Títọ́

Iṣẹ́ Ilé Ṣe Pàtàkì

Iṣẹ́ Ilé Ṣe Pàtàkì

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Nínú àwọn ìdílé kan, àwọn òbí máa ń yan àwọn iṣẹ́ ilé kan fún àwọn ọmọ, àwọn ọmọ náà sì máa ń fọwọ́ pàtàkì mú àwọn iṣẹ́ yìí. Àmọ́, nínú àwọn ìdílé míì, àwọn òbí kì í yan iṣẹ́ ilé fún àwọn ọmọ, àwọn ọmọ tí ò fẹ́ ṣiṣẹ́ ilé tẹ́lẹ̀ náà á wá kúkú jókòó gẹlẹtẹ.

Àwọn tó ń ṣèwádìí ti rí i pé ilẹ̀ Amẹ́ríkà àti Yúróòpù ni irú ìwà yìí pọ̀ sí jù, níbi tó jẹ́ pé ńṣe làwọn ọmọ kàn ń jẹ̀gbádùn lọ ràì wọn ò sì ṣe iṣẹ́ kankan nínú ilé. Bàbá kan tó ń jẹ́ Steven sọ pé: “Lóde òní, ńṣe làwọn òbí máa ń fi àwọn ọmọ sílẹ̀ táwọn ọmọ náà á sì máa gbá géèmù, wọ́n á máa lo íńtánẹ́ẹ̀tì, tàbí kí wọ́n máa wo tẹlifíṣọ̀n. Kò sẹ́ni tó yan iṣẹ́ kankan fún wọn.”

Kí lèrò rẹ? Yàtọ̀ sí pé iṣẹ́ ilé máa ń jẹ́ kí ilé wà ní mímọ́ tónítóní àti létòlétò, ǹjẹ́ ó tún ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè àwọn ọmọ?

OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀

Àwọn òbí kan kì í fẹ́ yan iṣẹ́ fáwọn ọmọ wọn, ní pàtàkì tí wọ́n bá rí i pé wọ́n ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àṣetiléwá àtàwọn iṣẹ́ ilé ìwé míì. Àmọ́, ronú nípa àǹfààní tó máa ṣe àwọn ọmọ náà.

Iṣẹ́ ilé máa ń jẹ́ káwọn ọmọ ní ìwà àgbà. Àwọn ọmọ tó bá ń ṣiṣẹ́ ilé sábà máa ń ṣe dáadáa níléèwé. Wọ́n máa ń ní ìgboyà, wọn kì í di àkẹ́bàjẹ́, wọ́n sì máa ń dúrò lórí ìpinnu wọn; àwọn nǹkan yìí sì ṣe pàtàkì fún ọmọ tó bá fẹ́ ṣàṣeyọrí nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Iṣẹ́ ilé máa ń jẹ́ káwọn ọmọ lè ran àwọn míì lọ́wọ́. Àwọn kan ti kíyè sí i pé àwọn ọmọ tí àwọn òbí máa ń yan iṣẹ́ ilé fún sábà máa ń wúlò fáwọn ará ìlú nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Ohun tó sì mú kí ọ̀rọ̀ rí bẹ́ẹ̀ ni pé ńṣe ni iṣẹ́ ilé ń kọ́ àwọn ọmọ láti máa ṣe ohun tó lè ṣe àwọn míì láǹfààní. Steven tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tún sọ pé: “Tó bá jẹ́ pé àwọn òbí kì í yan iṣẹ́ fún àwọn ọmọ wọn, ńṣe làwọn ọmọ náà á gbà pé àwọn ẹlòmíì ló gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo nǹkan fún àwọn. Tí wọ́n bá sì ṣe bẹ́ẹ̀ dàgbà, wọn ò ní mọ̀ pé téèyàn bá fẹ́ ṣàṣeyọrí láyé, áfi kó múra gírí, kó sì tẹpá mọ́ṣẹ́.”

Iṣẹ́ ilé máa ń jẹ́ kí ìdílé wà ní ìṣọ̀kan. Táwọn ọmọ bá ń ṣiṣẹ́ ilé, ó máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn wúlò gan-an nínú ilé àti pé àwọn náà ní ipá tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa kó kí nǹkan lè máa lọ dáadáa nínú ilé. Kò sí bí àwọn ọmọ á ṣe kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ ilé-ìwé àtàwọn ìgbòkègbodò ẹ̀yìn ilé ìwé nìkan làwọn òbí kà sí pàtàkì tí wọn ò sì jẹ́ káwọn ọmọ máa ṣiṣẹ́ ilé. Bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu kí ọmọ mi àtàwọn tí wọ́n jọ ń gbá bọ́ọ̀lù mọwọ́ ará wọn dáadáa ṣùgbọ́n tí òun àtàwọn tó wà nílé ò mọwọ́ ara wọn rárá?’

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn láti kékeré. Àwọn kan sọ pé látìgbà táwọn ọmọ bá ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́ta ni káwọn òbí ti máa yan iṣẹ́ ilé fún wọn. Àwọn míì tiẹ̀ sọ pé àwọn òbí lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe bẹ́ẹ̀ láti ọmọ ọdún méjì tàbí kó má tiẹ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ohun kan ni pé, àwọn ọmọ tó ṣì kéré gan-an máa ń fẹ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òbí wọn, wọ́n sì máa ń fẹ́ fara wé wọn.​—Ìlànà Bíbélì: Òwe 22:6.

Yan iṣẹ́ ilé tí kò pọ̀ ju ọjọ́ orí wọn lọ. Bí àpẹẹrẹ, o lè ní kí ọmọ ọdún mẹ́ta máa ṣa àwọn ohun ìṣeré, kí ó nu omi tó dà sílẹ̀ tàbí kó ṣa àwọn aṣọ tó ti dọ̀tí jọ. Àwọn ọmọ tó ti dàgbà lè fọ mọ́tò, wọ́n sì lè gbọ́unjẹ pàápàá. Má ṣe gbé iṣẹ́ tó ju agbára wọn lọ fún wọn. Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti rí bí àwọn ọmọ náà ṣe fara sí iṣẹ́ tó.

Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ ilé ṣe pàtàkì. Lóòótọ́, ó lè má rọrùn tó bá jẹ pé ojoojúmọ làwọn ọmọ rẹ máa ń ní iṣẹ́ àṣetiléwá tó pọ̀ láti ṣe. Ìwé The Price of Privilege sọ pé, tó bá jẹ́ pé torí kí àwọn ọmọ rẹ lè gbà máàkì tó pọ̀ ni o kò ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ilé, a jẹ́ pé “o ti gbé kẹ̀kẹ̀ ṣáájú ẹṣin nìyẹ̀n.” Bá a ṣe sọ ṣáájú, iṣẹ́ ilé máa ń jẹ́ káwọn ọmọ ṣe dáadáa níléèwé. Ìyẹn sì máa jẹ́ kí wọ́n kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó máa wúlò fún wọn nígbà tí àwọn náà bá ní ìdílé tiwọn.​—Ìlànà Bíbélì: Fílípì 1:10.

Fi sọ́kàn pé wọ́n lè má ṣe iṣẹ́ náà bó o ṣe fẹ́. Ó lè gbà ju àkókò tó o rò lọ kí ọmọ rẹ̀ tó parí iṣẹ́ tó o gbé fún un. O tún lè rí i pé tó bá jẹ́ pé ìwọ lo ṣe iṣẹ́ náà, wàá ṣe é dáadáa jù bẹ́ẹ̀ lọ. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe gba iṣẹ́ náà lọ́wọ́ rẹ̀. Kì í ṣe torí kí àwọn ọmọ rẹ lè ṣe iṣẹ́ náà dáadáa bíi ti àgbàlagbà ló ṣe gbé e fún wọn, àmọ́ torí kí wọn lè wúlò lọ́jọ́ ọ̀la, kí wọ́n sì rí ayọ̀ tó wà nínú kéèyàn fọwọ́ ara rẹ̀ ṣiṣẹ́.​—Ìlànà Bíbélì: Oníwàásù 3:22.

Máa fi àǹfààní tó máa ṣe wọ́n sọ́kàn. Àwọn kan sọ pé téèyàn bá ń fún ọmọ lówó kó lè ṣe iṣẹ́ ilé, ìyẹn máa jẹ́ kó wúlò. Àwọn míì sọ pé, ńṣe nìyẹn máa ń jẹ́ kí àwọn ọmọ gbájú mọ́ àǹfààní tí wọ́n máa rí jẹ nínú ìdílé wọn ju àwọn ohun tí wọ́n lè ṣe fún ìdílé wọn lọ. Wọ́n tún sọ pé, ọmọ kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọṣẹ́ tó bá ti lówó tó pọ̀, ìyẹn sì fi hàn pé kò ní rí àǹfààní tó wà nínú iṣẹ́ ilé nìyẹn. Kí nìyẹn kọ́ wa? Ohun tó máa dáa ni pé, tó o bá fẹ́ fún ọmọ lówó, fún un lowó, àmọ́ kì í ṣe torí iṣẹ́ ilé tó ṣe.