Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìlànà Nípa Lílò

Ìlànà Nípa Lílò

ÀKÍYÈSÍ PÀTÀKÌ: TÓ O BÁ LO ÌKÀNNÌ WA YÌÍ TÀBÍ TÓ O FI ÌSỌFÚNNI ÈYÍKÉYÌÍ NÍPA ARA RẸ RÁNṢẸ́ SÍ WA, O TI FÚN WA LÓMÌNIRA LÁTI LO GBOGBO ÌSỌFÚNNI TÓ O TẸ̀ SÓRÍ ÌKÀNNÌ YÌÍ NÍ ÌBÁMU PẸ̀LÚ ÒFIN LÍLO ÌSỌFÚNNI ARA ẸNI ÀTI NÍ ÌBÁMU PẸ̀LÚ ÀWỌN ÌLÀNÀ TÁ A KỌ SÍ ÌSÀLẸ̀.

 A FI ỌWỌ́ PÀTÀKÌ MÚ ÌSỌFÚNNI NÍPA RẸ

A máa rí i dájú pé a kò lo ìsọfúnni nípa rẹ lọ́nà tí kò yẹ. Ìlànà yìí sọ bá a ṣe ń lo àwọn ìsọfúnni tá a gbà lọ́wọ́ rẹ tàbí èyí tí ìwọ fúnra rẹ fi ránṣẹ́ sí wa. A máa ń tọ́jú àwọn ìsọfúnni kéékèèké nípa rẹ tó o bá wá sórí ìkànnì wa, a sì mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti pa ìsọfúnni náà mọ́. A tún mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ká jẹ́ kó o mọ ohun tá a máa lo ìsọfúnni náà fún. O lè yàn láti fi ìsọfúnni ara ẹni ránṣẹ́. “Ìsọfúnni ara ẹni” yìí lè jẹ́ orúkọ rẹ, àdírẹ́sì rẹ lórí ìkànnì, àdírẹ́sì tó o fi ń gba lẹ́tà, nọ́ǹbà fọ́ọ̀nù rẹ tàbí ìsọfúnni èyíkéyìí míì nípa ara rẹ. A ò béèrè ìsọfúnni kankan nípa ara rẹ tó o bá kàn fẹ́ lo ìkànnì wa láìfi àkáǹtì rẹ wọlé. Ọ̀rọ̀ náà “ìkànnì” tá a mẹ́nu bà tọká sí ìkànnì yìí àtàwọn míì tó so mọ́ ọn, bí apps.jw.org, ba.jw.org, stream.jw.org, àti wol.jw.org.

 BÁ A ṢE MÁA LO ÌSỌFÚNNI RẸ

Àjọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. (“Watchtower”) ló ni ìkànnì yìí, Ìlú New York ni àjọ yìí wà, a kì í fi í ṣòwò. Òun la fi ń ti iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lẹ́yìn, títí kan ẹ̀kọ́ Bíbélì tá à ń kọ́ àwọn èèyàn lọ́fẹ̀ẹ́. Tó o bá pinnu láti ṣí àkáǹtì sórí ìkànnì yìí tàbí o ṣe ọrẹ tàbí o béèrè pé ká kàn sí ẹ tàbí o fẹ́ ṣe ohun míì tó máa gba pé kó o fi ìsọfúnni nípa ara rẹ ránṣẹ́ sí wa, ńṣe lo fara mọ́ ìlànà yìí. O sì gbà pé ká fi ìsọfúnni nípa rẹ pa mọ́ sórí àwọn ìbi tá à ń tọ́jú ìsọfúnni sí lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. O tún gbà pé ká kó ìsọfúnni nípa rẹ jọ, ká tọ́jú rẹ̀ pa mọ́, ká sì fi ránṣẹ́ sí àjọ Watchtower àtàwọn ẹ̀ka míì tó ń ti iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn kárí ayé, kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ lórí ohun tó o béèrè fún. Oríṣiríṣi àjọ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò kárí ayé. Ibòmíì tá a tún lè fi ìsọfúnni ránṣẹ́ sí ni ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹ̀ka ọ́fíìsì míì tàbí àjọ míì tá à ń lò.

Ohun tó o bá lo ìkànnì wa fún ló máa pinnu ohun tá a máa fi ìsọfúnni rẹ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o fi owó tọrẹ lórí ìkànnì yìí ní orílẹ̀-èdè kan, a máa fi orúkọ rẹ àtàwọn ìsọfúnni míì tí wọ́n lè fi kàn sí ẹ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka wa ní orílẹ̀-èdè tó o ti fi owó tọrẹ. Tó bá sì jẹ́ pé o béèrè pé ká kàn sí ẹ, a máa fi orúkọ rẹ àtàwọn ìsọfúnni míì tá a lè fi kàn sí ẹ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí ẹ kí wọ́n bàa lè kàn sí ẹ.

Tí àwọn òfin nípa pípa ìsọfúnni mọ́ láṣìírí bá wà ní orílẹ̀-èdè tó ò ń gbé, lọ sí abala Ìlànà Pípa Àṣírí Mọ́ Láwọn Orílẹ̀-Èdè, wàá rí ìsọfúnni nípa orílẹ̀-èdè rẹ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ níbẹ̀.

 BÁ A ṢE MÁA PA ÌSỌFÚNNI RẸ MỌ́ LÁṢÌÍRÍ

Ọwọ́ kékeré kọ́ la fi mú àwọn ìsọfúnni rẹ, a dáàbò bò ó, a sì pá a mọ́ láṣìrí. Kódà àwọn ohun tá a fi ń tọ́jú àwọn ìsọfúnni rẹ jẹ́ ti ìgbàlódé, a sì ní àwọn ètò ààbò lóríṣìíríṣi kí àwọn ìsọfúnni rẹ má bàa tẹ àwọn míì lọ́wọ́, a ò ní pin káàkiri, a ò ní lò ó lọ́nà tí kò yẹ, a ò ní fi han ẹni tí kò yẹ, a ò ní ṣe àyípada kankan sí ìsọfúnni rẹ lẹ́yìn rẹ, a ò ní pá a rẹ́ àfi tó o bá ní ká ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ìsọfúnni rẹ kò sì ní di àwátì. Gbogbo àwọn tá a bá gbà láyè láti ṣiṣẹ́ lórí ìsọfúnni rẹ máa pa wọ́n mọ́ láṣìírí. Ìgbà tó bá yẹ ká tọ́jú àwọn ìsọfúnni rẹ dà la máa fi tọ́jú rẹ̀, ìyẹn sinmi lórí ìdí tó o fi fún wa láwọn ìsọfúnni náà, ó sì lè jẹ́ pé òfin ní ká fi wọ́n pa mọ́, tàbí kí wọ́n ṣì wà ní àkọọ́lẹ̀.

Tá a bá fẹ fi irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ráńṣẹ, a kì í fi ọ̀rọ̀ ààbò ṣeré, a máa ń lo ètò ìṣiṣẹ́ tó láàbò bíi Transport Layer Security (TLS). Àwọn kọ̀ǹpútà tí ó lójú àwọn tó lè lò ó, tá a tọ́jú pa mọ́ sáwọn ilé tó láàbò, tá a sì tún fi oríṣiríṣi àwọn ètò ìṣiṣẹ́ dáàbò bò ó là ń lò ká lè rí i dájú pé ìsọfúnni táwọn èèyàn fi ráńṣẹ́ sí wa kò bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará ìta. A máa ń tẹ̀lé àwọn ìlànà lórí ààbò délẹ̀ délẹ̀ kí ìsọfúnni rẹ má bàa tàfàlà.

 ÀWỌN ỌMỌDÉ

Tó o bá ṣì jẹ́ ọmọdé, tó o sì fẹ́ fi ìsọfúnni rẹ sórí ìkànnì wa, àwọn òbí rẹ tàbí alágbàtọ́ rẹ gbọ́dọ̀ fọwọ́ sí i. Òbí tàbí alágbàtọ́ tó bá gba ọmọdé kan láyè láti fi àwọn ìsọfúnni rẹ sórí ìkànnì yìí ti fara mọ́ Ìlànà Nípa LíLo Ìsọfúnni Ara Ẹni tó wà fún ìkànnì yìí.

 ÀWỌN NǸKAN TÁ A YÁ LÒ

Láwọn ìgbà míì, ìkànnì yìí máa ní ìlujá sí ìkànnì àwọn iléeṣẹ́ kan tá a ní kí wọ́n bá wa ṣe àwọn ohun kan (bí àpẹẹrẹ, àwọn fọ́ọ̀mù tá à ń lò lórí ìkànnì). Bó o ṣe máa mọ̀ pé o ti bọ́ sórí ìkànnì tó yàtọ̀ sí tiwa yìí ni pé àdírẹ́sì ìkànnì náà á yàtọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, tó o bá béèrè fún àwọn nǹkan kan lórí ìkànnì wa, ó lè gba e-mail tàbí àtẹ̀jíṣẹ́ látọ̀dọ̀ iléeṣẹ́ míì lórí ohun tó o béèrè. Ká tó yan àwọn iléeṣẹ́ tá a yá lò yìí, a máa ń rí i dájú pé wọ́n ní òfin tó máa pá ìsọfúnni àwọn ẹlòmíì mọ́ bíi ti ìkànnì wa. Àmọ́, àwọn ìkànnì tá a yá lò yìí tún máa ń ní àwọn ètò ìṣiṣẹ́ àtàwọn nǹkan míì tí a ò láṣẹ lórí ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe wọ́n, àdéhùn nípa lílò wọ́n àtàwọn ìlànà tó jẹ mọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ìsọfúnni ara ẹni pẹ̀lú àwọn ohun míì. Torí náà, tó o bá fẹ́ lo ètò ìṣiṣẹ́ wọn àtàwọn ohun tí wọ́n ń ṣe lórí ìkànnì yìí, o ní láti fara mọ́ àdéhùn ti lọ́ọ́lọ́ọ́ tí wọ́n bá ṣe. Wọn kì í sọ fún wa tí wọ́n bá yí àdéhùn náà pa dà, torí náà, yẹ àwọn àdéhùn náà wò kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ìkànnì tá a yá lò. Tó o bá ní ìbéèrè nípa òfin ọ̀kan lára àwọn iléeṣẹ́ tá a yá lò, lọ wo òfin tó wà lórí ìkànnì wọn.

 Bó o ṣe ń lo Google Maps lórí ìkànnì yìí, o ti fara mọ́ Àdéhùn Nípa Lílo Ìsọfúnni ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ti Google. Ìkànnì kan tá a yá lò ni Google, a ò sì láṣẹ lórí àwọn ètò ìṣiṣẹ́ wọn, ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe ohun tí wọ́n ń lò àtàwọn Ìlànà Tó Jẹ Mọ́ Iṣẹ́ Wọn. Torí náà, bó o ṣe ń lo Google Maps lórí ìkànnì yìí, o ti fara mọ́ àdéhùn lọ́ọ́lọ́ọ́ ti Google Maps/⁠Google Earth Additional Terms of Service. Wọn kì í sọ fún wa tí wọ́n bá yí àdéhùn náà pa dà, torí náà, yẹ àwọn àdéhùn nípa lílo Google Maps wò kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó. Má ṣe lo Google Maps tí o kò bá fara mọ́ àwọn àdéhùn wọn.

TÍ ÌLÀNÀ BÁ YÍ PA DA

 A ò dáwọ́ iṣẹ́ dúró lórí ìkànnì yìí, gbobo ìgbà là ń jẹ́ kí àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ túbọ̀ di èyí tó gbé pẹ́ẹ́lí sí i, a sì tún ń fi àwọn nǹkan tuntun míì kún un. Torí àwọn àyípadà yìí àti àwọn àyípada tó ń dé bá òfin àti ìmọ̀ ẹ̀rọ, àwa náà máa ń ṣe àwọn ìyípada tó bá yẹ sí bá a ṣe ń bójú tó àwọn ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì yìí. Tó bá pọn dandan ká ṣe àwọn àyípadà sí Ìlànà wa nípa àwọn ìsọfúnni tó wà lórí ìkànnì yìí, a máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ lórí abala yìí, kí ẹ̀yin náà lè mọ àwọn nǹkan tá à ń ṣe.

Ìlànà Ìṣiṣẹ́ Active Scrpting Tàbí JavaScript

Ìlànà ìṣiṣẹ́ tí wọ́n ń pè ní Scripting máa ń jẹ́ kí ìkànnì wa ṣe àwọn nǹkan pàtó kan. Ó máa ń jẹ́ kí ìkànnì náà tètè fún ẹ ní ìsọfúnni tó o fẹ́. Ìkànnì yìí kì í lo “scripting” láti fi ètò ìṣiṣẹ́ míì sórí kọ̀ǹpútà rẹ, a kì í sì í lò ó láti gba ìsọfúnni tá ò lẹ́tọ̀ọ́ sí lọ́wọ́ rẹ.

Kí àwọn apá kan lára ìkànnì yìí tó lè ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, o gbọ́dọ̀ tan “Active Scripting” tàbí “JavaScript” lórí ètò tá a fi ń ṣí àwọn ìkànnì, ìyẹn browser. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ètò tá a fi ń ṣí ìkànnì ló máa ní ibi téèyàn ti lè tan àwọn nńkan yìí fún àwọn ìkànnì kan. Wo ìsọ̀rí tó wà fún ìrànwọ́ lórí ètò tó o fi ń ṣí ìkànnì lórí ẹ̀rọ láti lè mọ bó o ṣe lè mú kí “scripting” ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìkànnì kan.