Wọ́n Jẹ́ Olóòótọ́ Nígbà Àdánwò
Wo bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ran àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́ nígbà tí wọ́n kojú àdánwò ìgbàgbọ́.
Wọ́n Lẹ Àmì Onígun Mẹ́ta Aláwọ̀ Pọ́pù Mọ́ Aṣọ Wọn
Kí nìdí táwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ kan fi wá ń mẹ́nu kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n bá ń kọ́ni nípa àwọn tí Ìjọba Násì fìyà jẹ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́?
Ilé Olódi Tí Wọ́n ti Dán Ìgbàgbọ́ Àwọn Èèyàn Jèhófà Wò
Ilé olódi kan wà lórílẹ̀-èdè Sípéènì tí wọ́n ti fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ológun.
A Kò Ní Sẹ́ Ìgbàgbọ́ Wa
Daniel Lokollo rántí inúnibíni tí wọ́n ṣe sí i lẹ́wọ̀n.
Wọ́n Ń Sin Jèhófà, Bí Ọ̀tá Tiẹ̀ Ń Gbógun
Báwo ni ìwà ipá táwọn èèyàn ń hù sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Jọ́jíà ṣe rí lára àwọn aráàlú?
Mo Pinnu Pé Ọmọ Ogun Kristi Ni Màá Jẹ́
Wọ́n ju Demetrius Psarras sẹ́wọ̀n torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológún. Síbẹ̀ kò fi Ọlọ́run sílẹ̀ láìka àwọn àdánwò lílekoko tó kojú.
Ó Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n
Nígbà tí ọkùnrin kan wà lẹ́wọ̀n ní Eritrea, ó fojú ara rẹ̀ rí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn sílò.
Mo Máa Ń Gbàdúrà Lórí Igi Ràgàjì Kan
Bàbá Rachel ń fi onírúurú nǹkan fa ojú rẹ̀ mọ́ra, ó sì ń lù ú ní àlùbami kó lè fi òtítọ́ sílẹ̀. Báwo ni àdúrà tó ń gbà lórí igi ràgàjì kan ṣe ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ alágbára àti adúróṣinṣin?
Ìwé pélébé lábẹ́ ẹ̀rọ ìfọṣọ
Ìyá kan wá ọgbọ́n dá sí bó ṣe máa kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì.
Wọ́n Fi Pẹ̀lẹ́tù Dá Àlùfáà Kan Tínú Ń Bí Lóhùn
Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa hùwà tútù, kódà tí wọ́n bá múnú bí wa. Ǹjẹ́ ìmọ̀ràn yìí wúlò lóòótọ́?
“O Da Mi Loju Pe Ijoba Olorun Maa De”
Won fi Efraín De La Cruz si ogba ewon meje otooto, won si lu u ni alubami tori pe o n waasu ihin rere. Ki lo se ti itara re ko fi din ku fun ogota [60] odun?
Akínkanjú Aṣáájú-ọ̀nà
Jálẹ̀ 60 ọdún tí André Elias fi ṣiṣẹ́ sìn, ó jólóòótọ́ bí wọ́n tiẹ̀ halẹ̀ mọ́ ọn tí wọ́n sì ń fọ̀rọ̀ lọ ọ́ nífun.
Mo Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Ọlọ́run àti Pẹ̀lú Màmá Mi
Nígbà tí Michiyo Kumagai pa ìjọsìn àwọn baba ńlá tì, àárín òun àti màmá rẹ̀ ò gún mọ́. Báwo ló ṣe wá pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú màmá rẹ̀?

