Ìrántí Ikú Jésù
Monday, March 22, 2027
Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe Ìrántí Ikú Jésù bó ṣe pa á láṣẹ nígbà tó sọ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.”—Lúùkù 22:19.
A pe ìwọ àti ìdílé ẹ pé kẹ́ ẹ wá síbẹ̀.
Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè
Àwọn wo ló lè wá síbẹ̀?
Gbogbo èèyàn la pè. O lè máwọn ọ̀rẹ́ ẹ àtàwọn ará ilé ẹ wá.
Báwo ni ètò náà ṣe máa pẹ́ tó?
Ó máa tó wákàtí kan.
Ibo lẹ ti máa ṣe é?
Béèrè lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ kí wọ́n lè sọ ibi tí wọ́n á ti ṣe é.
Ṣé màá san owó ìwọlé?
Rárá.
Ṣé ẹ máa gbé igbá ọrẹ?
Rárá. A kì í gbégbá ọrẹ láwọn ìpàdé wa.—Mátíù 10:8.
Ṣé ó nírú aṣọ tí mo gbọ́dọ̀ wọ̀?
Rárá. Àmọ́, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń múra lọ́nà tó fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣe pàtàkì yìí.
Báwo lẹ ṣe máa ń ṣe Ìrántí Ikú Jésù?
A máa gbọ́ àsọyé kan tó máa jẹ́ ká mọ ìdí pàtàkì tí Jésù fi kú àti bá a ṣe lè jàǹfààní látinú nǹkan tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa. Orin àti àdúrà la máa fi bẹ̀rẹ̀ ìtòlésẹẹsẹ náà, òun náà la sì máa fi parí ẹ̀.
Kó o lè mọ̀ sí i, wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí ẹ̀ ní “Kí Nìdí Tí Ọ̀nà Tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gbà Ń Ṣe Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Fi Yàtọ̀ sí Ti Àwọn Ẹlẹ́sìn Tó Kù?”
Ìgbà wo lẹ máa ṣe Ìrántí Ikú Jésù lọ́jọ́ iwájú?
2027: Monday, March 22
2028: Sunday, April 9
2029: Thursday, March 29

