Ìhìn Rere Látọ̀dọ̀ Jésù

Nínú ọ̀wọ́ fídíò yìí, wàá mọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà aráyé.

Ìhìn Rere Látọ̀dọ̀ Jésù—Ohun Tó Wà Nínú Fídíò Náà

Wo fídíò yìí kó o lè rí àwọn nǹkan tí Ìwé Ìhìn Rere sọ nípa Jésù, bíi pé o wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n ṣẹlẹ̀.

Abala 1: Ìmọ́lẹ̀ Tòótọ́ fún Aráyé

Báwo ni aráyé ṣe máa bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù? Mèsáyà nìkan ló lè gbà wá là.

Abala 2: “Èyí Ni Ọmọ Mi”

Jòhánù Arinibọmi tún ọ̀nà ṣe de Mèsáyà. Wàá rí àwọn nǹkan àgbàyanu tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ láyé!

Abala 3: ‘Èmi ni Ẹni Náà’

Jésù sọ fún Nikodémù pé òun ni Mèsáyà, ó tún sọ fún obìnrin ará Samáríà àtàwọn ará ìlú Násárẹ́tì, àmọ́ ìwọ̀nba èèyàn tó ní ọkàn tó tọ́ ló gbà pé òun ni Mèsáyà lóòótọ́. Lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ ìyanu kan tó lágbára, ó ní kí àwọn apẹja kan tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ máa tẹ̀ lé òun.

Abala 4: “Ìdí Tí Mo Ṣe Wá Nìyí”

Jésù fi hàn pé òun lè wo àwọn èèyàn sàn, òun sì lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Àmọ́, àwọn kan ta ko iṣẹ́ tó ń ṣe, wọ́n sì fẹ́ pa á. Bí Jésù ṣe fàánú hàn tó sì kọ́ni lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ mú kó lè sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, kó sì yan àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ méjìlá.

Abala 5: “Bó Ṣe Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́ Yà Wọ́n Lẹ́nu”

Lẹ́yìn tí Jésù wo ọ̀pọ̀ èèyàn sàn, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn náà lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, àwọn olùkọ́ wọn ò sì kọ́ wọn bẹ́ẹ̀ rí. Ẹnu ya àwọn èèyàn náà sí ọlá àṣẹ tó ní, bó ṣe ń lo àpèjúwe àti bó ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè máa fi ẹ̀kọ́ náà sílò lójoojúmọ́.

Abala 6: “Ṣé Ìwọ Ni Ẹni Tó Ń Bọ̀?”

Jésù fi hàn pé òun lágbára láti jí àwọn tó ti kú dìde. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe àtàwọn ohun tó kọ́ni fi ohun tó wà lọ́kàn àwọn tó ń gbọ́rọ̀ ẹ̀ hàn. Jésù lo àpèjúwe láti ṣàlàyé àwọn ohun kan nípa Ìjọba Ọlọ́run.

Ìtọ́wò Fídíò Ìhìn Rere Látọ̀dọ̀ Jésù

Wo ìtọ́wò fídíò táá jẹ́ kó o rí ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere bí i pé ó ṣojú ẹ.