Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 4, 2019
OHUN TUNTUN

Iye Èdè Orí Ìkànnì Wa Ti Yí Pa Dà

Iye Èdè Orí Ìkànnì Wa Ti Yí Pa Dà

Ọ̀nà tá à ń gbà sọ iye èdè táwọn èèyàn ti lè rí ìtẹ̀jáde lórí ìkànnì wa ti yí pa dà. Àwọn èdè tó jẹ́ pé lẹ́tà tí wọ́n fi ń kọ wọ́n nìkan ni wọ́n fi yàtọ̀ síra ò ní sí lára àwọn èdè tó wà lábẹ́ “Yan Èdè Rẹ” lórí ìkànnì wa mọ́. Bí àpẹẹrẹ, èdè Serbian (lọ́nà ti Cyrillic) àti èdè Serbian (lọ́nà ti Roman) ti di ẹyọ kan lórí ìkànnì wa báyìí, wọn kì í ṣe méjì. Torí náà, iye èdè tó wà lábẹ́ “Yan Èdè Rẹ” ti dín kù. A máa ṣe ìyípadà kan náà sí Àká Ìwé Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti ètò JW Library.