OCTOBER 9, 2019
OHUN TUNTUN
Inú Ìkànnì JW.ORG Lẹ Ti Máa Rí Ìkànnì JW Broadcasting Báyìí
Ní báyìí, inú ìkànnì jw.org lẹ ti máa rí ìkànnì JW Broadcasting ìyẹn tv.jw.org.
A sì ti yí orúkọ apá tá a pè ní ìtẹ̀jáde lórí ìkànnì jw.org pa dà sí Ohun Tá A Ní, torí pé apá náà ti wá ní àwọn àtẹ́tísí àti fídíò nínú. Ní báyìí, ẹ lè rí gbogbo fídíò lórí ìkànnì jw.org títí kan àwọn fídíò tó máa n wà lórí ìkànnì tv.jw.org nìkan tẹ́lẹ̀. Ẹ máa rí wọn ní abala OHUN TÁ A NÍ > FÍDÍÒ.
Kò ní sí apá tá a pè ní Ètò Tó Ń Lọ Lọ́wọ́ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ lórí ìkànnì tv.jw.org. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo apá tó wà lábẹ́ Wo Fídíò Lóríṣiríṣi ló ti ní ìlujá kan tá a pè ní Wo Àwọn Fídíò. Tẹ ìlujá yìí tó o bá fẹ́ wo gbogbo fídíò tó wà ní abala náà láì tò wọ́n tẹ̀ léra.
Lọ wo abala Fídíò lórí ìkànnì jw.org/yo.

