Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Òfin Pípa Àṣírí Mọ́ àti Títọ́jú Ìsọfúnni Kéékèèké

Òfin Pípa Àṣírí Mọ́ àti Títọ́jú Ìsọfúnni Kéékèèké

Ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lo ìsọfúnni ara ẹni téèyàn bá fún wọn nílòkulò, bíi kí wọ́n máa pín in fáwọn ẹlòmíì láìgba àṣẹ́. Fún ìsọfúnni nípa Àdéhùn Láti Pa Àṣírí Mọ́ tá à ń tẹ̀lé kárí ayé, tẹ ìlujá yìí.

Àdéhùn Láti Pa Àṣírí Mọ́ yìí ṣàlàyé bí ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń lo ìsọfúnni ara ẹni téèyàn bá fún wọn. Láfikún sí i, àlàyé tó wà nísàlẹ̀ yìí sọ àwọn ìlàná pàtó tó jẹ mọ́ ìlò ìkànní yìí.

Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc. (“Watchtower”) ló ni ìkànnì yìí. New York ní Watchtower wà, òun ni iléeṣẹ́ tó ń bójú tó bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí aye. Àmọ́, Watchtower kì í ṣe ilé iṣẹ́ tó ń ṣòwò o. Orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ní ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀rọ tó ń gbé ìkànnì yìí jáde wà.

Ìsọfúnni Nípa Ara Rẹ

Tó o bá fi ìsọfúnni nípa ara rẹ ránṣẹ́ lórí ìkànnì yìí, mọ̀ pé ohun tí a bá sọ fún ẹ pé a fẹ́ lo ìsọfúnni náà fún la máa lò ó fún.

A kò ní fún ẹlòmíì ní ìsọfúnni tó o tẹ̀ ránṣẹ́ nípa ara rẹ àyàfi tó bá pọn dandan láti ṣe bẹ́ẹ̀ ká lè ṣe ohun tó o béèrè fún, tàbí tó bá jẹ́ pé a ti sọ fún ẹ tẹ́lẹ̀ tàbí tí àwọn agbófinró bá bèèrè fún ìsọfúnni náà lábẹ́ òfin, tàbí tó bá jẹ́ pé a ò fẹ́ kí wọ́n lù wá ní jìbìtì tàbí ṣe wá ní jàǹbá. Ó sì tún lè jẹ́ pé a fẹ́ fi mú ẹni tó lù wá ní jìbìtì tàbí tó ṣe wá ní jàǹbá tàbí kó jẹ́ pé ó fẹ́ da ẹ̀rọ wa rú. Tó o bá lo ìkànnì yìí, ò fi hàn pé o fọwọ́ sí i pé ká fún àwọn ẹlòmíì ní ìsọfúnni nípa ara rẹ fún kìkì àwọn ohun tá a kọ sókè yìí. A ò ní fi ìsọfúnni tó o tẹ̀ ránṣẹ́ nípa ara rẹ pawó lọ́nàkọnà.

Àwọn Iléeṣẹ́ Tá A Yá Lò. Láwọn ìgbà míì, ìkànnì yìí máa ní ìlujá sí ìkànnì àwọn iléeṣẹ́ kan tá a ní kí wọ́n bá wa ṣe àwọn ohun kan (bí àpẹẹrẹ, àwọn fọ́ọ̀mù tá à ń lò lórí ìkànnì). Bó o ṣe máa mọ̀ pé o ti bọ́ sórí ìkànnì tó yàtọ́ sí tiwa yìí ni pé àdírẹ́sì ìkànnì náà á yàtọ̀, àwọ̀ rẹ̀ á sì yátọ̀ sí eléyìí. Ká tó yan àwọn iléeṣẹ́ tá a yá lò yìí, a máa ń rí i dájú pé wọ́n ní òfin tó máa pá ìsọfúnni àwọn ẹlòmíì mọ́ tó jọ ti ìkànni wa. Tó o bá ní ìbéèrè nípa òfin ọ̀kan lára àwọn iléeṣẹ́ tá a yá lò, lọ wo òfin tó wà lórí ìkànnì wọn.

Ètò Ààbò

A kò fi ọ̀rọ̀ ààbò ṣeré tó bá dọ̀rọ̀ ìsọfúnni nípa ara ẹni. A kì í fi irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ tàfàlà. Tá a bá fẹ fi irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ráńṣẹ, a máa ń lo ètò ìṣiṣẹ́ tó láàbò bíi Transport Layer Security (TLS). Àwọn kọ̀ǹpútà tí ó lójú àwọn tó lè lò ó, tá a tọ́jú pa mọ́ sáwọn ilé tó láàbò, tá a sì tún fi oríṣiríṣi àwọn ètò ìṣiṣẹ́ dáàbò bò ó là ń lò ká lè rí i dájú pé ìsọfúnni táwọn èèyàn fi ráńṣẹ́ sí wa kò bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará ìta.

Àkáǹtì Orí Ìkànnì Yìí

Àdírẹ́sì lẹ́tà orí íńtánẹ́ẹ́tì, tá a ń pè ní e-mail, tó o tẹ̀ ránṣẹ́ nígbà tó ò ń ṣí àkáǹtì lórí ìkànnì yìí la ó máa fi bá ẹ sọ̀rọ̀ nípa àkáǹtì tó o ṣí sórí ìkànnì yìí. Bí àpẹẹrẹ, tí o bá gbàgbé orúkọ tó ò ń lò tàbí ọ̀rọ̀ ìwọlé rẹ, tó o sì béèrè fún ìrànlọ́wọ́, inú àdírẹ̀sì lẹ́tà orí íńtánẹ́ẹ́tì tó wà ní abala ìsọfúnni nípa rẹ la máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Ọrẹ

Tó o bá fowó ṣètọrẹ lórí ìkànnì yìí, a máa gba orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ. Káwọn èèyàn bàa lè rọ́nà lo káàdì tá a fi ń rajà láti fi ṣètọrẹ, a máa ń lo àwọn ìkànnì tá a fi ń sanwó, ìyẹn àwọn tó lórúkọ lára wọn, tí wọn kì í sì í fi ìsọfúnni àwọn èèyàn tàfàlà. A ò lè rí ìsọfúnni tó o fi ráńṣẹ́ nípa káàdì rẹ, nọ́ńbà àkáǹtì rẹ tàbí ìsọfúnni nípa àkáǹtì rẹ, bẹ́ẹ̀ la kì í tọ́jú àwọn ìsọfúnni yìí pa mọ́. Báǹkì tó bá gba ọrẹ náà máa ń tọ́jú ìsọfúnni nípa ọjọ́, iye àti ibi tó o san ọrẹ náà sí sọ́wọ́ fún ọjọ́ mẹ́wàá. Èyí á jẹ́ ká lè fèsì tó o bá ní ìbéèrè nípa ọrẹ tó o ṣe, ohun tí òfin àkọsílẹ̀ owó sì sọ náà nìyẹn. A ò ní kàn sí ẹ pé kó o fowó kún ọrẹ tó o ṣé.

Àwọn Nǹkan Míì

O lè fi ìsọfúnni nípa ara rẹ (bí orúkọ rẹ, àdírẹ́sì àti nọ́ńbà fóònù rẹ) sórí ìkànnì yìí kó o lè ṣe àwọn nǹkan míì yàtọ̀ sí kó o ṣe ọrẹ tàbí ṣí àkáǹtì (bíi kó o béèrè ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀fẹ́). A máa gba ìsọfúnni yìí, àá tọ́jú ẹ̀, àá sì lò ó fún ohun tó o ní ká ṣe, a ò ní lò ó fún nǹkan míì yàtọ̀ síyẹn, á sì wà lọ́wọ́ wa níwọ̀n ìgbà tá a bá ṣì nílò rẹ̀.

Lílo Ìsọfúnni Kéékèèké àti Àwọn Ohun Míì Tó Jọ Ọ́

Tó o bá wọ ìkànnì wa, ojú ẹsẹ̀ la máa ń gba àwọn ìsọfúnni kan sílẹ̀. A máa ń lo “àwọn ìsọfúnni kéékèèké,” “àwọn àmì orí ìkànnì” àtàwọn ohun míì tó jọ ọ́. Nínú òfin pípa ìsọfúnni mọ́ yìí, a lo ọ̀rọ̀ náà “ìsọfúnni kéékèèké” fáwọn nǹkan míì tó jọ ọ́, bí i “local storage,” ìyẹn títọ́jú ìsọfúnni pa mọ́ lórí ìkànnì.

Ìsọfúnni Kéékèèké. Tó o bá lọ sórí ìkànnì yìí, ó máa tọ́jú ìsọfúnni kékeré kan tá à ń pè ní “cookie” pa mọ́ sórí fóònù, tablet tàbí kọ̀ǹpútà tó o lò. Bó ṣe rí lórí ọ̀pọ̀ ìkànnì náà nìyẹn. Oríṣiríṣi ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ló wà, iṣẹ́ wọn sì yàtọ̀ síra, àmọ́ gbogbo wọn ló máa jẹ́ kó o lè gbádùn ìkànnì yìí tó o bá ń lò ó. Ìsọfúnni kékeré yẹn máa ń jẹ́ ká mọ̀ bóyá o ti lo ìkànnì yìí rí, ó sì lè jẹ́ ká rántí àwọn ohun tó o yàn láàyò nígbà tó ò ń lo ìkànnì náà. Bí àpẹẹrẹ, a lè fi ìsọfúnni nípa èdè tó o yàn pa mọ́, kó lè jẹ́ pé tó o bá pa dà lọ sórí ìkànnì yìí, èdè yẹn ni kọ̀ǹpútà máa yàn fúnra ẹ̀. A kì í fi àwọn ìsọfúnni kéékèèké tá a gbà sílẹ̀ yìí polówó ọjà fún onítọ̀hún.

A lè pín àwọn ìsọfúnni kéékèèké tá a máa ń gbà sílẹ̀ lórí ìkànnì yìí sọ́nà mẹ́ta:

  1. Ìsọfúnni Tó Pọn Dandan​—Àwọn ìsọfúnni yìí máa jẹ́ kó o lè ṣe àwọn ohun kan lórí ìkànnì yìí, bíi kó o wọlé pẹ̀lú àkáǹtì ẹ tàbí kó o kọ̀wé kún inú fọ́ọ̀mù lórí ìkànnì. Láìsí àwọn ìsọfúnni kéékèèké yìí, o ò ní rí àwọn ohun tó o fẹ́ ṣe, bí àpẹẹrẹ, o ò ní lè ṣe ọrẹ. Àwọn ìsọfúnni kéékèèké yìí tún máa jẹ́ ká lè ṣe ohun tí ìwọ fúnra ẹ bá béèrè fún tó o bá ń lo ìkànnì wa. Kì í gba ìsọfúnni nípa ara ẹ, ká wá máa fi polówó ọjà tàbí ká máa fi tọ́jú gbogbo ibi tó o dé lórí íńtánẹ́ẹ̀tì.

  2. Ìsọfúnni Tó Ṣe Pàtàkì​—Àwọn ìsọfúnni yìí máa ń jẹ́ kí ìkànnì wa lè rántí àwọn ohun tó o yàn (bí àpẹẹrẹ, orúkọ tó o fi ṣí àkáǹtì, èdè tàbí àgbègbè tó o wà) ó sì máa jẹ́ kó o túbọ̀ gbádùn ìkànnì wa tó o bá ń lò ó.

  3. Ìsọfúnni Tá A Fi Ń Ṣèwádìí​—Àwọn ìsọfúnni yìí máa ń jẹ́ ká mọ báwọn èèyàn ṣe ń lo ìkànnì yìí tó, bí àpẹẹrẹ, iye èèyàn tó ń lò ó tàbí bí wọ́n ṣe ń pẹ́ tó lórí ẹ̀. Ohun kan ṣoṣo tó ń mú ká gba ìsọfúnni yìí ni pé ó máa ń jẹ́ ká lè mú kí ìkànnì yìí sunwọ̀n sí i.

Àwọn ìsọfúnni kan wà tó jẹ́ pé ìkànnì wa nìkan ló ń gbà á. Àmọ́ àwọn kan wà tó jẹ́ pé ìkànnì míì ló ń gbà á. Àwọn ìsọfúnni tí ìkànnì wa ń gbà nìkan la máa ń lò, àfi àwọn ìsọfúnni tó jẹ mọ́ ètò Google reCAPTCHA látọ̀dọ̀ ìkànnì Google. Ètò Google reCAPTCHA yìí ni ìkànnì Google fi máa ń mọ̀ bóyá èèyàn ló ń lo kọ̀ǹpútà àbí ẹ̀rọ rọ́bọ́ọ̀tì táwọn kan máa ń lò láti fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tí ò mọ̀ wọ́n rí. Wo òfin pípa àṣírí ìkànnì Google mọ́ ní https://www.google.com/intl/en/policies/privacy/.

Àmì Orí Ìkànnì. Àwọn abala orí ìkànnì wa máa ń ní àwọn àmì kéékèèké kan tó máa ń jẹ́ ká lè rí àwọn ìsọfúnni kan gbà, bí àpẹẹrẹ, ó máa jẹ́ ká mọ̀ tó o bá ṣí abala kan pàtó. A máa ń fi àwọn àmì orí ìkànnì yìí mọ báwọn èèyàn ṣe ń lò ó tó, ká sì mọ bó ṣe ń ṣiṣẹ́ sí.

Lílo àdírẹ́sì IP. Àdírẹ́sì IP ni nọ́ńbà tí íńtánẹ́ẹ̀tì fi máa ń dá kọ̀ǹpútà rẹ mọ̀. A máa ń lo àdírẹ́sì IP àwọn tó bá ń lọ sórí ìkànnì yìí àti irú browser, ìyẹn ètò tó ń ṣí ìkànnì sórí ẹ̀rọ, tí wọ́n ń lò ká lè mọ bí wọ́n ṣe ń lo ìkànnì yìí, ká sì mọ ìṣòro tí wọ́n máa ń ní lórí ẹ̀ àti ohun tá a lè ṣe kí àtilọ sórí ìkànnì náà lè rọ̀ wọ́n lọ́rùn.

Ọwọ́ Ẹ Ló Kù Sí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ browser ló lè jẹ́ kó o tẹ nǹkan kan ká má bàa rí ìsọfúnni kankan tọ́jú tó o bá lọ sórí ìkànnì wa tàbí kó fún ẹ láyè láti fọwọ́ sí i bóyá o fẹ́ kí a tọ́jú ìsọfúnni kankan pa mọ́ sórí fóònù rẹ. Jọ̀ọ́, lọ wo ìtọ́ni tó wà fún browser rẹ kó o lè mọ bí wàá ṣe ṣe é. Àmọ́ a fẹ́ kó o mọ̀ pé tá ò bá rí ìsọfúnni kankan tọ́jú nígbà tó o bá lọ sórí ìkànnì wa, o lè máà rí gbogbo tó o fẹ́ ṣe lórí ìkànnì wa.

Ìlànà Ìṣiṣẹ́ Active Scripting tàbí JavaScript

“Scripting” (ìyẹn ìlànà ìṣiṣẹ́ tó máa ń jẹ́ kí kọ̀ǹpútà lè ṣe ohun tẹ́ni tó ń lò ó fẹ́ kó ṣe) máa ń mú kí ọ̀nà tí ìkànnì gbà ń ṣiṣẹ́ sunwọ̀n sí i. Ó máa ń jẹ́ kí ìkànnì náà tètè pèsè ìsọfúnni fún ẹ. Ìkànnì yìí kì í lo “scripting” láti fi ètò ìṣiṣẹ́ sórí kọ̀ǹpútà rẹ, a kì í sì í lò ó láti gba ìsọfúnni tá ò lẹ́tọ̀ọ́ sí lọ́wọ́ rẹ.

Kí àwọn apá kan lára ìkànnì yìí tó lè ṣiṣẹ́ bó ṣe tọ́, o gbọ́dọ̀ jẹ́ kí yálà “Active scripting” tàbí “JavaScript” máa ṣiṣẹ́ lórí ètò tó ń ṣí ìkànnì sórí ẹ̀rọ, ìyẹn browser. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ètò tó ń ṣí ìkànnì sórí ẹ̀rọ ló máa ní ibi téèyàn ti lè mú kí àwọn ohun tá a sọ yìí ṣiṣẹ́ tàbí kí wọ́n má ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìkànnì kan. Wo ìsọ̀rí tó wà fún ìrànwọ́ lórí ètò tó ń ṣí ìkànnì sórí ẹ̀rọ láti lè mọ bó o ṣe lè mú kí “scripting” ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìkànnì kan.

Àwọn Ẹ̀tọ́ Tó O Ní

O lè lo ìkànnì yìí lọ́fẹ̀ẹ́, o sì lè wa ìtẹ̀jáde èyíkéyìí, o sì lè wa fídíò tàbí ètò tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ jáde lọ́fẹ̀ẹ́. Kò pọn dandan kó o ṣí àkáǹtì, kó o ṣe ọrẹ tàbí kó o ṣe ohunkóhun tó máa gba pé kó o fi ìsọfúnni ara ẹ sórí ìkànnì yìí kó o lè gbádùn ẹ̀. Àmọ́, tó bá wù ẹ́ láti ṣí àkáǹtì, ṣe ọrẹ, béèrè ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ọ̀fẹ́ tàbí tó wù ẹ́ láti ṣe ohunkóhun tó máa gba pé kó o fi ìsọfúnni ara ẹ sórí ìkànnì yìí, a jẹ́ pé o fọwọ́ sí Òfin Pípa Àṣírí Mọ́ àti Títọ́jú Ìsọfúnni Kéékèèké yìí, o sì tún fọwọ́ sí i pé ká tọ́jú àwọn ìsọfúnni rẹ sórí àwọn ẹ̀rọ íńtánẹ́ẹ̀tì wa tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti pé kí iléeṣẹ́ Watchtower àtàwọn ètò míì tó ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣiṣẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè míì gba ìsọfúnni rẹ, kí wọ́n ṣètò rẹ̀, kí wọ́n fi ránṣẹ́, kí wọ́n sì fi pa mọ́ torí àtiṣe ohun tó o fẹ́. Ohun tó o bá ṣe lórí ìkànnì náà ló máa pinnu ìsọfúnni tá a máa béèrè. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ṣe ọrẹ fún iléeṣẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kan tórúkọ wọn wà lábẹ́ òfin orílẹ̀-èdè wọn, a máa fún iléeṣẹ́ náà ní orúkọ àti àdírẹ́sì rẹ, bó o ṣe rí i lórí ìkànnì nígbà tó o fé ṣe ọrẹ. Àpẹẹrẹ míì nìyí, tó o bá béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a máa fún ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orúkọ rẹ kí wọ́n lè ṣètò bí wọ́n á ṣe kàn sí ẹ.

Tó ò bá fún wa ní gbogbo ìsọfúnni tá a béèrè lọ́wọ́ ẹ kó o lè ṣí àkáǹtì, ṣe ọrẹ tàbí kó o lè ṣe ohunkóhun tó o fẹ́ lórí ìkànnì yìí, o ò ní lè rí ohun tó o fẹ́ ṣe.

Bó bá pọn dandan pé ká ṣàtúnṣe sí Òfin Pípa Àṣírí Mọ́ àti Títọ́jú Ìsọfúnni Kéékèèké, a máa gbé àtúnṣe náà sí abala yìí, kó o lè mọ ìsọfúnni tá a ń gbà àti bí a ṣe lò ó.

Òfin ṣì lè fún ẹ láwọn ẹ̀tọ́ míì tó máa jẹ́ kó o lè ṣe ohun tó o fẹ́ sí ìsọfúnni rẹ lórí ìkànnì yìí, ó lè fún ẹ lẹ́tọ̀ọ́ láti rí ìsọfúnni ara ẹ tó wà lórí ìkànnì yìí, láti ṣàtúnṣe sí i tàbí kó o yọ ọ́ kúrò. Tí èyí bá ń ṣiṣẹ́ lórílẹ̀-èdè rẹ, wàá rí ìsọfúnni nípa bó o ṣe lè kàn sí wa níbí. Tó o bá fẹ́ béèrè ohun kan nípa ìsọfúnni ara ẹ tó o fi sórí ìkànnì yìí nígbà tó o ṣe ọrẹ, jọ̀ọ́ kàn sí iléeṣẹ́ tá a sọ fún ẹ pé a máa fi ẹ̀bùn rẹ ránṣẹ́ sí nígbà tó ò ń ṣe ọrẹ náà, tá a sì tún kọ sínú rìsíìtì rẹ.