Àfikún ìsọfúnni: Ó dùn wá gan-an pé ìjì líle Hurricane Harvey pa arábìnrin wa kan tó jẹ́ àgbàlagbà.

NEW YORK—Lọ́jọ́ Friday, August 25, 2017, ìjì runlérùnnà kan tí wọ́n ń pè ní Hurricane Harvey ṣọṣẹ́ lágbègbè Rockport, Texas, tó wà létíkun. Nígbà tó máa fi di ọjọ́ Sunday, ìjì náà ti rọlẹ̀ díẹ̀, àmọ́ ó ṣì ń ṣọṣẹ́ lọ láwọn ibì kan ní Texas títí di ọjọ́ Wednesday, August 30. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ṣèwádìí láti mọ bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe nípa tó lórí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa.

Nǹkan bí 84,000 àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìjì líle náà ṣàkóbá fún. Kò sí arákùnrin tàbí arábìnrin wa kankan tó kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, àmọ́ àwọn mẹ́sàn-án ló fara pa, àwọn márùn-ún sì ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye wọn jẹ́ 5,566 ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti sọ di aláìnílé lórí. Ilé àwọn ará wa tí ó tó 475 ni ìjì yẹn bà jẹ́ gan-an; láfikún síyẹn, ilé àwọn ará wa míì tí iye rẹ̀ jẹ́ 1,182 ló tún bà jẹ́.

Àwọn alábòójútó àyíká tó wà ní ìlú Austin, Dallas, àti San Antonio ló ń ṣe kòkáárí bí àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣàkóbá fún ṣe máa rí ìrànwọ́ gbà. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa tó wà láwọn ìlú yìí ló gba àwọn ará tó wá láti Houston àti Texas Gulf Coast tí ilé wọn bà jẹ́ sílé. Àwọn ará wa míì fi òbítíbitì oúnjẹ ránṣẹ́, wọ́n tún fi omi àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì ṣètìlẹ́yìn fáwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣàkóbá fún.—Òwe 3:27; Hébérù 13:1, 2.

Àwọn alábòójútó àyíká jẹ́ ká mọ̀ pé gbogbo àwọn ìjọ tó wà láwọn ìlú náà ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí wọn nìṣó. Àwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lóríllẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa lọ ṣèbẹ̀wò sáwọn àgbègbè tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ kí wọ́n lè tù wọ́n nínú, kí wọ́n sì ṣètìlẹ́yìn tó bá yẹ fún wọn.

David A. Semonian tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “A bá àwọn tí ìjì líle Harvey ṣàkóbá fún kẹ́dùn gan-an ni, a sì tún dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé. À ń gbàdúrà fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣàkóbá fún. A tún ń rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa bá a nìṣọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, Ọlọ́run ìfẹ́.”—Sáàmù 55:8, 22; Aísáyà 33:2; 40:11.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000