Òjò rọ̀ gan-an ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti July 6 sí July 12, 2017, ó sì mú kí omi yalé àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ Èkó, Niger àti Ọ̀yọ́. Ìròyìn tá a gbọ́ ni pé, ó kéré tán, èèyàn méjìdínlógún [18] ni ẹ̀mí wọn ti lọ sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà ti wádìí, wọ́n sì ti rí i pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ìkankan ò sì fara pa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mẹ́rin nínú wọn ò nílé lórí mọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ilé Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ló bà jẹ́, ilé ẹnì kan sì wà tó bà jẹ́ pátápátá. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Nàìjíríà ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará wọn àtàwọn aládùúgbò wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, táwọn kan nínú wọn náà ò nílé lórí mọ́.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000

Nàìjíríà: Paul Andrew, +234-7080-662-020