Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Thursday, September 7, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára gan-an wáyé ní apá gúùsù Etí Òkun Pàsífíìkì ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò. Ìmìtìtì ilẹ̀ yẹn ló le jù nínú àwọn èyí tó ti wáyé rí ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, èèyàn márùnlélógójì [45] ló pa. Ó dùn wá pé a gba ìsọfúnni pé arákùnrin wa kan àti àwọn arábìnrin wa méjì wà lára àwọn tó kú.

Ní àfikún sí ìyẹn, ìsọfúnni tá a kọ́kọ́ gbà fi hàn pé ọ̀pọ̀ ilé àwọn ará wa àti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ló bàjẹ́ tàbí tó bàjẹ́ pátápátá. Gbọ̀ngàn Àpéjọ méjì ní Ìpínlẹ̀ Chiapas náà bàjẹ́. Àmọ́ wọ́n ṣì ń bá àyẹ̀wò lọ.

A ó túbọ̀ máa gbàdúrà fún àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa, a nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa tù wọ́n nínú, á sì fún wọn lókun.—2 Tẹsalóníkà 2:16, 17.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Mexico: Gamaliel Camarillo, +52-555-133-3048