Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún [100] ọdún báyìí tí ojú ọjọ́ ti yí pa dà láwọn ibì kan lórílẹ̀-èdè Íńdíà, èyí sì ti mú kí mànàmáná tó léwu gan-an máa kọ, kí òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá sì máa rọ̀, kódà àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ pé òjò ò rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí lórílẹ̀-èdè náà. Omi àti yẹ̀pẹ̀ tó ya ti ba nǹkan jẹ́ lọ́pọ̀ ìlú lórílẹ̀-èdè náà; àwọn tí ẹ̀mí wọn lọ sí i tó ọgọ́rùn-ún méje [700], ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn ni ò sì nílé lórí mọ́.

Títí di July 31, 2017, a ò tíì gbọ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ṣèṣe tàbí pé wọ́n fara pa yánnayànna. Àmọ́, ó kéré tán, ilé mẹ́ta tó jẹ́ tàwọn Ẹlẹ́rìí ni omi ya wọ̀, ṣùgbọ́n kò bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Íńdíà ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará wọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000

Íńdíà: Tobias Dias, +91-9845476425