Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JUNE 27, 2017
UNITED KINGDOM

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣèrànwọ́ Lẹ́yìn Tí Iná Jó Ilé Kan Kanlẹ̀ Nílùú London

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣèrànwọ́ Lẹ́yìn Tí Iná Jó Ilé Kan Kanlẹ̀ Nílùú London

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí nílùú London. Láàárọ̀ kùtù ọjọ́ Wednesday, June 14, 2017, iná jó ilé gogoro Grenfell Tower kanlẹ̀, ilé alájà mẹ́rìnlélógún [24] kan tó wà ní àdúgbò North Kensington nílùú London, ó sì ṣọṣẹ́ gan-an. Àwọn aláṣẹ sọ pé ó kéré tán, èèyàn mọ́kàndínlọ́gọ́rin [79] ló kú sínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Mẹ́rin làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n mú kúrò nínú ilé náà, ilé gogoro Grenfell Tower yẹn ni méjì nínú wọn ń gbé. A dúpẹ́ pé ìkankan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí ò fara pa, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé wọn wà lára àwọn ilé tó jóná kanlẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé nítòsí ilé tí iná ti ṣọṣẹ́ yìí ń fún ará wọn àtàwọn ìdílé wọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí ní oúnjẹ, aṣọ àti owó tí wọ́n lè fi tọ́jú ara wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí tún ń fi Bíbélì tu àwọn tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú ládùúgbò North Kensington.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

United Kingdom: Andrew Schofield, +44-​20-​8906-​2211