Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JULY 25, 2017
UKRAINE

Àwọn Aláṣẹ Wá Wo Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-èdè Ukraine

Àwọn Aláṣẹ Wá Wo Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-èdè Ukraine

ÌLÚ LVIV, ní Ukraine—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ukraine ṣe àkànṣe ètò kan, wọ́n ṣí ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn tó wà ní Ukraine sílẹ̀ ní May 2, 2017 káwọn èèyàn lè wá wò ó. Àbẹ̀wò ọlọ́jọ́ kan yìí jẹ́ káwọn aláṣẹ ìlú, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìwé àtàwọn oníṣòwò, títí kan àwọn aráàlú Lviv, ráyè wá wo bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa.

Ibi tí wọ́n ṣe fáwọn ọmọdé rèé.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ṣètò àwọn ìpàtẹ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, títí kan àwọn àwòrán àti fídíò kan tó ṣàlàyé bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Wọ́n tún ṣètò ibì kan tí wọ́n kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí àti ibì kan tó wà fáwọn ọmọdé. Ivan Riher, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ukraine, sọ pé: “Látọdún 2001, ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tá a máa ṣí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa fáwọn èèyàn pé kí wọ́n wá wò ó. Lóòótọ́, àwọn aráàlú mọ̀ wá mọ bá a ṣe máa ń lọ kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti ilé dé ilé, àmọ́ inú wa dùn gan-an láti pe àwọn aládùúgbò wa kí wọ́n wá wo bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa àti ipa rere tó ń ní lórí ìlú.”

Àwọn tó wá síbi tí wọ́n kó àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé sí kà nípa ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ukraine, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

Andriy Yurash, alága Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn àti Ẹ̀yà.

Andriy Yurash, tó jẹ́ alága Ẹ̀ka Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn àti Ẹ̀yà, lábẹ́ Iléeṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Bójú Ọ̀rọ̀ Àṣà ní Ukraine, sọ bí iṣẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ṣe wú u lórí tó, ó ní: “Àpẹẹrẹ rere làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́, wọ́n jẹ́ ká rí ohun tí ẹ̀sìn kan lè ṣe láti pa kún ìṣọ̀kan ìlú, kí àlàáfíà sì wà láàárín àwọn ẹlẹ́sìn náà àtàwọn èèyàn míì.”

Lọ́dún yìí, àwa Ẹlẹ́rìí tún ti ṣe irú nǹkan yìí ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù àti ní oríléeṣẹ́ wa tó wà ní Warwick, nílùú New York.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Ukraine: Ivan Riher, +38-032-240-9323