Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JANUARY 31, 2017
THAILAND

Àwọn Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè Thailand Ń Fi Ìwé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ran Àwọn Aráàlú Lọ́wọ́ Kí Ìlú Lè Dàgbà Sókè

Àwọn Aláṣẹ Orílẹ̀-èdè Thailand Ń Fi Ìwé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ran Àwọn Aráàlú Lọ́wọ́ Kí Ìlú Lè Dàgbà Sókè

ÌLÚ BANGKOK—Àwọn aláṣẹ ìjọba lórílẹ̀-èdè Thailand ń fi ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba lẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ bíi: Báwọn òbí ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ wọn dáadáa, bí àwọn ọkọ ò ṣe ní máa lu ìyàwó wọn tàbí kí wọ́n máa lu ọmọ nílùkulù àti bí wọ́n ṣe lè mú kí ìlera wọn dáa sí i, kí ọpọlọ sì jí pépé. Oṣù yìí ló pé ọdún mẹ́ta tí àwọn aláṣẹ lórílẹ̀-èdè Thailand ti ń fi ìwé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ran àwọn aráàlú lọ́wọ́.

Ìjọba orílẹ̀-èdè Thailand ti ṣètò ibi ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún méje [8,700] sáwọn ìlú láti máa dá àwọn aráàlú lẹ́kọ̀ọ́ káàkiri lórílẹ̀-èdè náà. Yàtọ̀ síyẹn, ìjọba tún ṣètò ibi ìdálẹ́kọ̀ọ́ mọ́kànlá [11] lọ́tọ̀, tí wọ́n ti ń dá àwọn aṣíwájú láwùjọ lẹ́kọ̀ọ́. Chaiwat Saengsri, tó jẹ́ olùdarí ibi ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó wà fáwọn aṣíwájú lágbègbè Nakhon Nayok, ní àríwá ìlà oòrùn ìlú Bangkok, ló wà láàárín nínú fọ́tò tó wà lókè yìí. Ọkùnrin náà sọ pé: “Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe wú mi lórí, torí ìdí tí wọ́n fi ń ṣe àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe yé mi. Wọ́n fẹ́ máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láwùjọ kí wọ́n lè túbọ̀ mọ Ẹlẹ́dàá sí i. Àwa náà fẹ́ ran àwọn aráàlú lọ́wọ́ káyé wọn lè dáa sí i, kí wọ́n lè ní àlàáfíà, káyé wọn sì lè nítumọ̀.” Ó tún sọ pé: “Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwé ìròyìn Jí! àpilẹ̀kọ kan tó sọ pé ‘Bí Ẹ Ṣe Lè Yẹra Fún Sísọ Ọ̀rọ̀ Líle Síra Yín’ sọ àwọn kókó kan, ohun kan náà sì ni Ilé Iṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ìdàgbàsókè Ìlú àti Ààbò Aráàlú fẹ́ fi kọ́ àwọn aṣíwájú láwùjọ. Àpilẹ̀kọ yẹn ràn wá lọ́wọ́ gan-an, òun la fi dá wọn lẹ́kọ̀ọ́.” Nígbà tó yá, Ọ̀gbẹ́ni Chaiwat ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó àwọn ìwé wọn wá síbi ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n pè ní SMART Leader, tí wọ́n ṣe fáwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Ọgọ́rùn-ún [100] aṣíwájú ìlú àtàwọn olùkọ́ tí wọ́n jẹ́ ogún [20] ló wá láti àgbègbè méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí ìdàgbàsókè ìlú àti bí wọ́n á ṣe máa darí àwọn aráàlú. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Ọ̀gbẹ́ni Chaiwat nínú fọ́tò tó wà lókè yìí.

Anthony Petratyotin, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Thailand sọ pé: “Inú wa dùn pé àwọn aláṣẹ ìlú ń fi ìmọ̀ràn Bíbélì tó wà nínú àwọn ìwé wa ṣe àwọn aráàlú láǹfààní. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ipasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń rí ìwé wa gbà, àá máa rí i pé àwọn aláṣẹ ń rí ìwé wa lò.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Thailand: Anthony Petratyotin, +66-2-375-2200