Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

JUNE 7, 2017
SRI LANKA

Ọ̀gbàrá Òjò àti Ẹrẹ̀ Ṣọṣẹ́ Gan-an ní Siri Láńkà

Ọ̀gbàrá Òjò àti Ẹrẹ̀ Ṣọṣẹ́ Gan-an ní Siri Láńkà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣiṣẹ́ kára láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ará wọn àti àwọ̀n míì tí ọ̀gbàrá òjò àti ẹrẹ̀ tó ya ṣe lọ́ṣẹ́ ní gúúsù àti ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Siri Láńkà. Òjò tó bẹ̀rẹ̀ ní May 26 ló fa ọ̀gbàrá òjò àti ẹrẹ̀ tó ya náà. Ìròyìn sọ pé iye èèyàn tó ju igba [200] ló kú, tí àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [77,000] ò sì nílé lórí mọ́.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Siri Láńkà ṣètò ìgbìmọ̀ méjì tó ń ṣètò ìrànwọ́ láti pèsè ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] nílò gbàrà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé. Ara àwọn ohun tí wọ́n kọ́kọ́ pèsè ni oúnjẹ àti ilé fún àwọn tó pàdánù ilé wọn. A ò gbọ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ.

Láti oríléeṣẹ́ wa ní New York ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bójú tó bí a ṣe ń fi owó táwọn èèyàn fi ń ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù wa kárí ayé ṣèrànwọ́ nígbà àjálù.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Siri Láńkà: Nidhu David, +94-11-2930-444