Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

NOVEMBER 27, 2012
SOUTH KOREA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Àjọyọ̀ Ọgọ́rùn-ún Ọdún ní Korea

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Àjọyọ̀ Ọgọ́rùn-ún Ọdún ní Korea

SEOUL, Korea—Oṣù pàtàkì ni November ọdún 2012 jẹ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ní orílẹ̀-èdè South Korea, torí oṣù náà ló pé ọgọ́rùn-ún ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lórílẹ̀-èdè yẹn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ń pín ìwé ìléwọ́ kan láti fi ṣe àjọyọ̀ náà tí wọ́n sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ó ti pé ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí táwọn ti wà lórílẹ̀-èdè náà. Ìwé ìléwọ́ aláwọ̀ mèremère olójú ewé mẹ́rin náà ṣàlàyé ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè South Korea ní ṣókí àtàwọn ohun tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ fún àǹfààní àwọn èèyàn.

Ọdún 1912 ni aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní orílẹ̀-èdè Korea. Ní báyìí, iye Bíbélì èdè Korea tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tẹ̀ jáde ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ márùndínlógójì [700,000] wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin [70,000] lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé wọn lọ́fẹ̀ẹ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè náà lé ní ẹ̀ẹ́dégbèje [1,300], ìjọ kọ̀ọ̀kan sì ń ṣe àwọn ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ níbi tí wọn ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbogbo èèyàn ló sì lè wá síbẹ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe àwọn àpéjọ lọ́dọọdún ní orílẹ̀-èdè Korea, ọdún 1954 ni wọ́n ṣe àpéjọ àkọ́kọ́ níbẹ̀. Wọ́n máa ń ṣe àwọn àpéjọ yìí ní èdè míì yàtọ̀ sí èdè Korea, láti ọdún 1997, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe é ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Korea pẹ̀lú. Ní ọdún 2009, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe àpéjọ àgbáyé ní ìlú Seoul, àwọn tó sì wá síbẹ̀ lé ní ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [58,000], àwọn ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [6,500] lára wọn ló sì wá láti orílẹ̀-èdè mọ́kànlá míì. Ọdún 1953 ni a dá ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní ìlú Seoul sílẹ̀.

Dae-il Hong, tó ń gbẹnu sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Korea sọ pé: “Inú wá dùn pé ó ti pé ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí tí a ti ń ran àwọn èèyàn wa lọ́wọ́.” Ó wá ṣàlàyé pé: “A gbà gbọ́ pé téèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, ó máa jẹ́ kí tọkọtaya ṣera wọn lọ́kan, kí ìdílé láyọ̀, ó sì máa jẹ́ kí àdúgbò tòrò. À ń fojú sọ́nà fún ọ̀pọ̀ ọdún tá a ṣì máa fi ran àwọn èèyàn wa lọ́wọ́.”

Media Contacts:

J. R. Brown, Office of Public Information, tel. +1 718 560 5000

Republic of Korea: Dae-il Hong, tel. +82 10 3951 0835