Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

OCTOBER 14, 2015
RUSSIA

Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Ò Fọwọ́ sí Bí Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Ṣe Fòfin De Ìkànnì JW.ORG

Àwọn Ọ̀jọ̀gbọ́n Ò Fọwọ́ sí Bí Ìjọba Orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà Ṣe Fòfin De Ìkànnì JW.ORG

ST. PETERSBURG, Rọ́ṣíà—Ní July 21, 2015, ìjọba àpapọ̀ Rọ́ṣíà fòfin de ìkànnì jw.org ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n á sì fẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kan ẹnikẹ́ni tó bá lo ìkànnì náà tàbí lọ sórí rẹ̀. Ní gbogbo ayé, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà nìkan ni wọ́n ti fòfin de ìkànnì jw.org.

Yekaterina Elbakyan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìsìn àti ọ̀jọ̀gbọ́n ní ilé-ìwé Academy of Labor and Social Relations nílùú Moscow, sọ nípa ìkànnì jw.org pé: “Ohun tí mo rò ni pé ìkànnì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí pọn dandan torí ó jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè fẹnu ara wọn sọ òótọ́ nípa ẹ̀sìn wọn fáráyé, kìí ṣe ọ̀rọ̀ wọ́n-ní-wọ́n-pé . . .  Yàtọ̀ sí pé àwọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí ìkànnì yìí àwọn tó tún fẹ́ràn ẹ̀sìn lóríṣiríṣi pẹ̀lú fẹ́ràn ẹ̀. Ká tiẹ̀ pa ti àwọn onímọ̀ ìsìn bíi tèmi tì, àwọn akọ̀ròyìn àtàwọn aṣojú ilé iṣẹ́ tí wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ nípa ìsìn náà fẹ́ràn ẹ̀ pẹ̀lú.”

“Ohun tí mo rò ni pé ìkànnì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí wúlò gan-an torí ó jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè fẹnu ara wọn sọ òótọ́ nípa ẹ̀sìn wọn fáráyé.”—Yekaterina Elbakyan, Ọ̀jọ̀gbọ́n ní iléèwé Academy of Labor and Social Relations nílùú Moscow

Lev Levinson tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ òfin láti Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn nílùú Moscow, kọ ọ̀rọ̀ nípa ohun tí ìjọba ṣe yìí pé: “Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti ṣe àwọn òfin tó gba àwọn èèyàn láyè láti ṣe ẹ̀sìn tí wọ́n bá fẹ́, kí wọ́n sì péjọ pọ̀. Síbẹ̀, bí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ń gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n sì ń fòfin de àwọn ìkànnì, ṣe ni wọ́n ò jẹ́ káwọn èèyàn lómìnira láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn wọn. Àfi bíi pé wọ́n tún pa dà sí àwọn òfin amúnisìn tí wọ́n lò làwọn ọdún 1801 si 1900. Àwọn adájọ́ àtàwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan ló sì ń gbé àwọn ìlànà tí kò bófin mu yìí kalẹ̀, tí wọ́n ń fi ti pé àwọn ń gbéjà ko àwọn agbawèrèmẹ́sìn bojú.”

Látọdún 2013 ni ọ̀rọ̀ òmìnira ẹ̀sìn yìí ti wà nílé ẹjọ́, bí wọ́n ṣe fòfin de ìkànnì jw.org yìí ló wá fọba lé e. Ní August 7, 2013, ilé ẹjọ́ àdúgbò kan nílẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe ẹjọ́ bòókẹ́lẹ́ kan, ó sì kéde pé ìkànnì wa jẹ́ ìkànnì àwọn “agbawèrèmẹ́sìn”, àmọ́ ní January 22, 2014 ilé ẹjọ́ ìpínlẹ̀ yí ẹjọ́ náà pa dà. Igbá kejì Agbẹjọ́rò Àgbà Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà wá pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, pé kí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tún ẹjọ́ náà dá. Ní December 2, 2014, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí agbẹjọ́rò náà mú wá láì pe àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé kí wọ́n wá gbèjà ara wọn. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ náà wá sọ pé ìkànnì wa jẹ́ ìkànnì àwọn “agbawèrèmẹ́sìn”, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ náà sọ pé kò sí ìkankan nínú ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kò fọwọ́ sí lórí ìkànnì náà. Àwa Ẹlẹ́rìí ò fọwọ́ sí ẹjọ́ tí wọ́n dá yìí, torí náà, àwa náà pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, a kọ̀wé sí alága Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, àmọ́ pàbó ló já sí. Nítorí ẹjọ́ tí wọ́n dá yìí, nígbà tó di July 21, 2015, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà pe ìkànnì wa ní ìkànnì àwọn agbawèrèmẹ́sìn, wọ́n sì fòfin dè é jákèjádò Rọ́ṣíà.

Yaroslav Sivulskiy tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà sọ̀rọ̀ nípa ipa tí ìfòfindè náà ní, ó sọ pé: “Irú ìdájọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ìjọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe yìí ò múnú wa dùn rárá. Ìfòfindè yìí ṣèdíwọ́ fún ìjọsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní 170,000 tó wà lórílẹ̀-èdè náà gan-an. Tẹ́ ẹ bá tún wá ronú kan àwọn tó tó 285,000 èèyàn tó máa ń ṣí ìkànnì yìí lójoojúmọ́, ẹ máa rí i pé kì í ṣe àwa Ẹlẹ́rìí nìkan ni ìfòfindè náà dí lọ́wọ́, kò tún jẹ́ káwọn míì tí kìí ṣe Ẹlẹ́rìí ríbi ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó mọ́yán lórí.”

Arákùnrin J. R. Brown tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé sọ ní orílé-iṣẹ́ wa ní Brooklyn, ìlú New York pé: “Ìkànnì jw.org láwọn fídíò tó ti gba àmì ẹ̀yẹ, àwọn ìwé táwọn èèyàn fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lónírúurú èdè, àtàwọn ìwé ìròyìn méjì táwọn èèyàn tíì pín kiri jù lọ láyé, ìyẹn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Wọ́n tún máa ń ṣí ìkànnì yìí sí àwọn ibi ìpàtẹ ìwé tó tóbi jù lọ, wọ́n sì tún ń lò ó láwọn iléèwé. Àìmọye àwọn èèyàn kárí ayé ló ti jàǹfààní lórí ìkànnì yìí, wọ́n sì tún lò ó gan-an lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ká sòótọ́, ìkànnì tó yẹ kí gbogbo èèyàn gbárùkù tì ni ìkànnì yìí.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000

Russia: Yaroslav Sivulskiy, tel. +7 812 702 2691