Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

APRIL 6, 2017
RUSSIA

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Ṣì Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Ṣì Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Lọ́jọ́ kejì tí ilé ẹjọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbọ́rọ̀ lẹ́nu Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́, tí wọ́n ń sọ pé kí ìjọba ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà pa. Ilé ẹjọ́ dá ìgbẹ́jọ́ náà dúró díẹ̀, wọ́n wá sún un di Friday, April 7, 2017, ní aago mẹ́wàá àárọ̀.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn ní New York ṣàlàyé pé: “Ìgbẹ́jọ́ tòní jẹ́ kó ṣe kedere pé gbogbo ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ń sọ nípa ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀.” Ó fi kún un pé, “Àmọ́ a tún kíyè sí i lónìí pé Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ gbà lóòótọ́ pé tí wọ́n bá fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀rọ̀ náà máa le débi pé tí wọ́n bá kóra jọ lásán láti gbàdúrà, wọ́n lè mú wọn pé ọ̀daràn ni wọ́n. À ń retí pé kí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ dá ẹjọ́ yìí bó ṣe tọ́, kí wọ́n má sì jẹ́ kí àwọn aláṣẹ fi ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tá a ní dù wá.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, +7-812-702-2691