Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

APRIL 19, 2017
RUSSIA

Ọjọ́ Karùn-ún tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Gbọ́ Ẹjọ́: Wọ́n Gbé Ohun tí Ojú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Rí Lórí Ọ̀rọ̀ Òfin Láti Ọ̀pọ̀ Ọdún Sẹ́yìn Yẹ̀ Wò

Ọjọ́ Karùn-ún tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Gbọ́ Ẹjọ́: Wọ́n Gbé Ohun tí Ojú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Rí Lórí Ọ̀rọ̀ Òfin Láti Ọ̀pọ̀ Ọdún Sẹ́yìn Yẹ̀ Wò

NEW YORK—Ní Wednesday, April 19, 2017, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] èèyàn ló kóra jọ sílé ẹjọ́ (àwọn kan tiẹ̀ ti jí débẹ̀ láti aago méjì òru) ní ọjọ́ karùn-ún tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà máa gbọ́ ẹjọ́ tó dá lórí ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ pé kí wọ́n ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa. Àwọn tọ́rọ̀ kàn kó ìwé mẹ́tàlélógójì [43] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ wá sílé ẹjọ́ lọ́jọ́ náà, ìsọfúnni kún inú rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí. Ara ohun tó wà nínú rẹ̀ ni àlàyé nípa bí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ṣe ti ń hùwà ipá sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ohun tó lé ní ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.

Ilé Ẹjọ́ yẹ ìwé mẹ́tàlélógójì [43] tí àwọn tọ́rọ̀ kàn kó wá sílé ẹjọ́ wò.

Nígbà tí ilé ẹjọ́ ń yẹ àwọn ìwé náà wò, àwọn agbẹjọ́rò Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ò rí ẹ̀rí kankan lábẹ́ òfin tó lè mú kí ìjọba ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà pa, wọn ò sì rí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn tàbí ní ìkankan nínú ibi tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Yury Toporov, ọ̀kan lára àwọn agbẹjọ́rò Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà, jẹ́ kí Ilé Ẹjọ́ mọ̀ pé àwọn àmì ẹ̀yẹ àtàwọn lẹ́tà ìdúpẹ́ tí ìjọba fún Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà wà lára àwọn ìwé táwọn kó wá sílé ẹjọ́ lọ́jọ́ náà. Èyí fi hàn pé àwọn aláṣẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà tẹ́lẹ̀, wọ́n gbà pé wọ́n ń pa kún ìlọsíwájú ìlú. Wọ́n tún rí i pé ohun kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ láwọn ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Yàtọ̀ síyẹn, ìsọfúnni tó wà nínú àwọn ìwé míì lára èyí tí wọ́n kó wá fi hàn pé àtọdún 2008 ni Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ti ń fimú fínlẹ̀ káàkiri láwọn ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní Rọ́ṣíà, àmọ́ wọn ò rí ohunkóhun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ agbawèrèmẹ́sìn níbẹ̀, àwọn agbẹjọ́rò Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sì gbà pé òótọ́ ni.

Àwọn tó wà nínú fọ́tò yìí, láti òsì lọ sí ọ̀tún: Anton Omelchenko, Maksim Novakov, Victor Zhenkov àti Yury Toporov, àwọn agbẹjọ́rò Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà. Ní ẹ̀yìn, láti òsì lọ sí ọ̀tún: Vasiliy Kalin àti Sergey Cherepanov (tí ẹ̀gbẹ́ kan orí rẹ̀ hàn), tí wọ́n jẹ́ ara ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà.

Ilé Ẹjọ́ wá sún ìgbẹ́jọ́ náà sí April 20, 2017, ní aago méjì ọ̀sán.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, +7-911-087-8009