Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

APRIL 5, 2017
RUSSIA

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Gbọ́ Ẹjọ́ Pàtàkì Kan—Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Gbọ́ Ẹjọ́ Pàtàkì Kan—Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

NEW YORK—Òní ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ kan tó dá lórí ẹ̀sùn tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ fi kan Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ pé kí ìjọba ti ẹ̀ka ọ́fíìsì náà pa. Lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà dé àyè kan, wọ́n sún un di Thursday, April 6, 2017, ní aago méjì ọ̀sán.

March 30, 2017 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé ẹjọ́ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, pé àwọn ò fara mọ́ ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ. Àmọ́ lónìí, kó tó di pé Ilé Ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ náà, Ilé Ẹjọ́ ti kọ́kọ́ sọ pé àwọn ò gba ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ. Wọn ò tún jẹ́ káwọn ọ̀jọ̀gbọ́n jẹ́rìí sí i pé ó ní ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ní lọ́kàn tí wọ́n fi fẹ̀sùn yìí kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọn ò sì tún jẹ́ káwọn míì tọ́rọ̀ ṣojú wọn jẹ́rìí sí i, àwọn tó rí i pé ṣe ni àwọn aláṣẹ lọ́ ẹ̀sùn irọ́ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́sẹ̀.

Ọ̀rọ̀ yìí ti kúrò ní kékeré, torí kárí ayé làwọn oníròyìn ti gbé e, kódà, àpilẹ̀kọ kan jáde nínú ìwé ìròyìn Time lórí ìkànnì ní April 4 (àkòrí rẹ̀ ni “Russian Supreme Court Considers Outlawing Jehovah’s Witness Worship”). Nígbà tó sì di April 5, àpilẹ̀kọ míì jáde lójú ìwé àkọ́kọ́ nínú ìwé ìròyìn The New York Times (àkòrí rẹ̀ ni “Pacifist, Christian and Threatened by Russian Ban as ‘Extremist’”).

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn ní New York sọ pé: “À ń retí pé kí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà gbèjà ẹ̀tọ́ táwọn ará wa ní lábẹ́ òfin ní Rọ́ṣíà, kí wọ́n lè lómìnira láti máa sin Ọlọ́run ní àlàáfíà. Ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló ń fara balẹ̀ wo ibi tọ́rọ̀ yìí ń lọ, tí wọ́n sì ń retí ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà máa ṣe, bóyá wọ́n á gbèjà àwọn ọmọ ilẹ̀ wọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí wọn kì í rúfin ìlú.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, +7-812-702-2691