Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

MARCH 21, 2017
RUSSIA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé Fẹ́ Sọ̀rọ̀ Síta Lórí Bí Ìjọba Ṣe Fẹ́ Fòfin De Ẹ̀sìn Wọn ní Rọ́ṣíà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kárí Ayé Fẹ́ Sọ̀rọ̀ Síta Lórí Bí Ìjọba Ṣe Fẹ́ Fòfin De Ẹ̀sìn Wọn ní Rọ́ṣíà

NEW YORK—Torí pé àwọn aláṣẹ ń halẹ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé àwọn máa tó fòfin de ẹ̀sìn wọn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé fẹ́ kọ lẹ́tà sí àwọn aláṣẹ tó wà ní Kremlin àtàwọn aláṣẹ Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ pé kí wọ́n gba àwọn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rọ àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ [8,000,000] káàkiri ayé pé kí wọ́n kọ lẹ́tà sáwọn aláṣẹ yìí.

Ní March 15, 2017, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Ilẹ̀ Rọ́ṣíà gbé ẹjọ́ kan wá sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ pé kí wọ́n kéde pé agbawèrèmẹ́sìn ni Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, kí wọ́n sì gbẹ́sẹ̀ lé e. Wọ́n tún ní kí Ilé Ẹjọ́ fòfin de ohun táwọn Ẹlẹ́rìí ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ bá fọwọ́ sí ohun tí wọ́n sọ yìí, wọ́n máa ti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí ìlú St. Petersburg pa. Tó bá yá, wọ́n lè fòfin de ibi ìjọsìn wọn tó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] tí wọ́n ti forúkọ rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin, wọ́n sì lè mú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [2,300] lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ní ọ̀daràn. Ìjọba lè gbẹ́sẹ̀ lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn, títí kan gbogbo ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n lè fẹ̀sùn ọ̀daràn kan gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run. Ẹjọ́ ọ̀hún ti wà ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, a sì ń retí kí wọ́n dájọ́ ní April 5.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wa sọ pé: “Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn nílé lóko dá sí ọ̀rọ̀ pàtàkì tó wà nílẹ̀ yìí. Àṣìlò òfin gbáà ni kí wọ́n máa fẹ̀sùn agbawèrèmẹ́sìn kan àwọn aráàlú tí kì í ṣe oníwàhálà, tí wọn kì í sì í rúfin, àfi bíi pé apániláyà ni wọ́n. Ẹ̀sùn èké pátápátá gbáà ni wọ́n fi kàn wọ́n yìí.”

Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa gbé irú ìgbésẹ̀ yìí nìyí. Ní nǹkan bí ogún [20] ọdún sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí kọ lẹ́tà gbèjà àwọn ará wọn ní Rọ́ṣíà nígbà tàwọn aláṣẹ kan tí agbára wà lọ́wọ́ wọn lásìkò yẹn ń bà wọ́n lórúkọ jẹ́ kiri. Yàtọ̀ síyẹn, láwọn ìgbà kan ní àwọn orílẹ̀-èdè míì bíi Jọ́dánì, Korea, àti Màláwì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ lẹ́tà sí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba pé kí wọ́n dáwọ́ inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn ará wọn dúró.

Ọ̀gbẹ́ni Semonian sọ pé: “Ó ṣe kedere pé a ò lè pe àwọn ẹlẹ́sìn tó jọ ń ka Bíbélì, tí wọ́n jọ ń kọrin, tí wọ́n sì ń gbàdúrà ní ọ̀daràn. À ń retí pé lẹ́tà tá a fẹ́ kọ kárí ayé yìí máa mú kí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà dáwọ́ ohun tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí ìjọba fẹ́ ṣe sáwọn ará wa yìí dúró.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, +7-812-702-2691