Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

APRIL 7, 2017
RUSSIA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sọ Tẹnu Wọn ní Ọjọ́ kẹta tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Wọn

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sọ Tẹnu Wọn ní Ọjọ́ kẹta tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Wọn

NEW YORK—Ọjọ́ kẹta tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ń gbọ́ ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dópin, Ilé Ẹjọ́ sì ti sún un di Wednesday, April 12, 2017, ní aago mẹ́wàá àárọ̀. Níbi ìgbẹ́jọ́ tòní, Ilé Ẹjọ́ gbọ́rọ̀ lẹ́nu Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin. Wọ́n mẹ́nu ba àwọn kókó pàtàkì láti fi hàn pé ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ pé kí ìjọba gbẹ́sẹ̀ lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ wọn kò tọ́.

Adájọ́ dojú oríṣiríṣi ìbéèrè kọ Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́, ó ní kí wọ́n mú ẹ̀rí wá pé agbawèrèmẹ́sìn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóòótọ́, àti pé ìwé agbawèrèmẹ́sìn ni wọ́n ń pín fáwọn èèyàn. Àmọ́ Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ò rí nǹkan kan sọ. Vasiliy Kalin, tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà, sọ fún Ilé Ẹjọ́ pé: “Mo fẹ́ kí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ mọ̀ pé àwọn èèyàn tó fẹ́ yín fẹ́re làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́ ẹ fẹ́ fòfin dè yìí, á sì dùn wọ́n gan-an tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀ torí pé wọn ò ro ibi rò yín.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, +7-911-087-8009