Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JUNE 21, 2017
RUSSIA

Fídíò Kan Jáde Lórí Bí Àwọn Aláṣẹ ní Rọ́ṣíà Ṣe Ya Wọ Ibi Táwọn Ẹlẹ́rìí Ti Ń Ṣèpàdé ní Ìrọwọ́rọsẹ̀

Fídíò Kan Jáde Lórí Bí Àwọn Aláṣẹ ní Rọ́ṣíà Ṣe Ya Wọ Ibi Táwọn Ẹlẹ́rìí Ti Ń Ṣèpàdé ní Ìrọwọ́rọsẹ̀

NEW YORK—Fídíò kan ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde lórí ìkànnì glavny.tv, látọ̀dọ̀ iléeṣẹ́ ìròyìn tó ń gbéròyìn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwọn ìlú tó wà ní ibi tí ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fìkàlẹ̀ sí. Fídíò yẹn dá lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní May 25, 2017, táwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ Rọ́ṣíà kan àtàwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba ti ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé ní ìrọwọ́rọsẹ̀ nílùú Oryol, ní Rọ́ṣíà.

Ní May 25, 2017, àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tó dira ogun ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣèpàdé ní ìrọwọ́rọsẹ̀ nílùú Oryol, ní Rọ́ṣíà.

A rí Dennis Christensen tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark nínú fídíò yẹn, tó rọra ń bá àwọn aláṣẹ sọ̀rọ̀. Ọjọ́ táwọn agbófinró wá yẹn ni wọ́n ti mú un, wọ́n sì ti tì ímọ́lé di ọjọ́ tí wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀.

Dennis Christensen tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark nìyẹn, tó ń bá àwọn aláṣẹ sọ̀rọ̀. Alàgbà ni nínú ìjọ, àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba sì ti fi sí àtìmọ́lé láti May 25, 2017.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn sọ pé: “Fídíò yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé èèyàn àlàáfíà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bí wọ́n sì ṣe máa ń ṣe nìyẹn kódà tí àwọn aláṣẹ bá ń dẹ́rù bà wọ́n, tí wọ́n sì ń kó wọn láyà jẹ kí wọ́n lè dí wọn lọ́wọ́ lásìkò tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Gbogbo bí àwọn aláṣẹ ò ṣe jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rímú mí yìí ò lè dáwọ́ dúró, àfi tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bá yí ẹjọ́ tí kò tọ́ tí wọ́n dá fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pa dà. Ọ̀rọ̀ Dennis Christensen tó jẹ́ arákùnrin wa náà tún ń ká wa lára gan-an. Wọn ò jẹ́ kí ìyàwó ẹ̀ wá kí i, wọn ò sì jẹ́ kó pè é lórí fóònù. À ń retí pé láìpẹ́, wọ́n á dá a sílẹ̀ ní àtìmọ́lé tí wọ́n fi sí láìtọ́ yìí.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000