Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

APRIL 12, 2017
RUSSIA

Àwọn Agbẹjọ́rò Tún Mú Ẹ̀rí Wá ní Ọjọ́ Kẹrin tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Àwọn Agbẹjọ́rò Tún Mú Ẹ̀rí Wá ní Ọjọ́ Kẹrin tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà Ń Gbọ́ Ẹjọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

NEW YORK—Ọjọ́ kẹrin rèé tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ti wà lẹ́nu ìgbẹ́jọ́ yìí, èrò sì kún ilé ẹjọ́ lọ́jọ́ náà. Wọ́n ṣì ń yiiri ohun tí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ sọ wò, pé kí ìjọba ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Rọ́ṣíà pa. Wọ́n gbọ́ ẹjọ́ náà títí di ọ̀sán, kó sì tó di ìrọ̀lẹ́, Ilé Ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ náà di Wednesday, April 19, 2017, ní aago mẹ́wàá àárọ̀.

Ọ̀dọ̀ àwọn agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ̀rọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, wọ́n sọ̀rọ̀ gbe Ẹ̀ka Ọ́fíìsì náà. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn agbẹjọ́rò Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Àwọn agbẹjọ́rò àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ẹ̀rí ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn, ni adájọ́ bá tìtorí èyí sọ fún Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ pé kí wọ́n sọ ohun pàtó tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tí wọ́n fi rúfin, tó máa mú kí ìjọba ti Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn pa. Àmọ́ àwọn agbẹjọ́rò Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ò rí nǹkan kan sọ sí ohun tí adájọ́ bi wọ́n àtàwọn ìbéèrè míì tí wọ́n bi wọ́n. Ilé ẹjọ́ gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn tí àwùjọ méjèèjì pè jẹ́rìí sọ́rọ̀ náà, ibẹ̀ ni ìgbẹ́jọ́ tọjọ́ yẹn parí sí.

Lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, a retí pé kí ilé ẹjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni kan lórí ẹjọ́ yìí.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Rọ́ṣíà: Yaroslav Sivulskiy, +7-911-087-8009