Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JUNE 8, 2017
RUSSIA

Ààrẹ Putin Fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àmì Ẹ̀yẹ “Òbí Tó Dára Jù Lọ”

Ààrẹ Putin Fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Àmì Ẹ̀yẹ “Òbí Tó Dára Jù Lọ”

NÍLÙÚ NEW YORK—Ní May 31, 2017, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Vladimir Putin fún Valeriy àti Tatiana Novik, òbí ọlọ́mọ mẹ́jọ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti ìlú Karelia, ní àmì ẹ̀yẹ “Òbí Tó Dára Jù Lọ” nígbà ayẹyẹ kan tí wọ́n ṣe ní Kremlin nílùú Moscow.

Wọ́n ṣe ayẹyẹ yẹn ní Kremlin ní ọjọ́ kan ṣáájú ọjọ́ ayẹyẹ àwọn ọmọdé.

Láti May 2008 ló ti wà pé kí ààrẹ máa fún àwọn òbí tó bá tọ́ sí, ní àmì ẹ̀yẹ “Òbí Tó Dára Jù Lọ.” Àmì ẹ̀yẹ yìí wà fún àwọn òbí tí wọ́n ní ó kéré tán ọmọ méje, tí wọ́n sì tọ́ gbogbo wọn yanjú tí àwọn ọmọ náà sì ní ìlera àti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó péye pẹ̀lú ìwà ọmọlúwàbí. Wọ́n gbà pé àwòfiṣàpẹẹrẹ ni àwọn òbí tí wọ́n bá fún ní àmì ẹ̀yẹ yìí jẹ́ láwùjọ.

Valeriy Novik, bàbá ọlọ́mọ mẹ́jọ ń gba àmì ẹ̀yẹ “Òbí Tó Dára Jù Lọ” láti ọwọ́ ààrẹ Putin.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wa tó wà ní ìlú Brooklyn, ní ìpínlẹ̀ New York sọ pé: “Àmì ẹ̀yẹ yìí jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé ẹ̀kọ́ Bíbélì ọ̀fẹ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn ti ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn yanjú kí wọ́n lè wúlò láwùjọ, kì í sì ṣe orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà nìkan ló ti ń wáyé bẹ́ẹ̀, jákèjádò ayé ni. A retí pé kí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà sọ̀rọ̀ nípa àmì ẹ̀yẹ tí Ààrẹ Putin fún àwọn òbí Ẹlẹ́rìí yẹn nígbà tí wọ́n bá ń tún ẹjọ́ wa gbé yẹ̀ wò ní July 17, 2017, ìyẹn ẹjọ́ tí wọ́n dá láti gbẹ́sẹ̀ lé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wa lórílẹ̀ èdè Rọ́ṣíà.”

Media Contact:

David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000