Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

APRIL 26, 2017
PHILIPPINES

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tún Àwọn Ilé Kọ́ Lẹ́yìn Tí Ìjì Super Typhoon Nock-Ten

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tún Àwọn Ilé Kọ́ Lẹ́yìn Tí Ìjì Super Typhoon Nock-Ten

ÌLÚ MANILA, ní Philippines—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Philippines ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ńlá lórí ṣíṣètò ìrànwọ́ láti tún àwọn ilé tó bà jẹ́ ṣe nígbà tí ìjì líle Super Typhoon Nock-Ten (táwọn aráàlú ń pè ní “Nina”) jà, kí wọ́n sì tún àwọn ilé tó bà jẹ́ kọjá àtúnṣe kọ́.

Jason Dotimas (lápá òsì) àti Bethel Alvarez (lápá ọ̀tún), Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé ni wọ́n. Wọ́n ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú Polangui, ní Philippines, kọ́. Ìrìn àjò tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé àádọ́ta [650] kìlómítà ni wọ́n rìn láti wá ṣèrànwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ yìí.

Ní December 25, 2016, ìjì Nock-Ten jà ní àgbègbè Bicol lórílẹ̀-èdè náà, ìjì ọ̀hún le gan-an, ó runlé rùnnà. Ìròyìn tá a gbọ́ ni pé ìjì náà pa èèyàn mẹ́wàá, ilé tó sì bà jẹ́ lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti àádọ́rùn-ún [390,000]. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò kú lágbègbè yẹn, ìkankan nínú wọn ò sì fara pa yánnayànna, ilé àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] àti ibi mẹ́rìnlélógún [24] tí wọ́n ti ń jọ́sìn (ìyẹn Gbọ̀ngàn Ìjọba) ló bà jẹ́, ṣe làwọn kan tiẹ̀ bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Philippines ti wá ṣètò ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù sílùú Naga, kí wọ́n lè ran àwọn Ẹlẹ́rìí tí àjálù yìí ṣẹlẹ̀ sí ìdílé wọn lọ́wọ́.

Dean Jacek, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Philippines sọ pé, “Látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìrànwọ́ yìí, àwọn ará wa tó yọ̀ǹda ara wọn ti bá wa tún ilé àwọn ará wa tó jẹ́ igba àti mọ́kànléláàádọ́rin [271] ṣe, wọ́n sì ti tún Gbọ̀ngàn Ìjọba méjìlélógún [22] ṣe. Àwọn ará wa tó ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé yìí á ṣì máa báṣẹ́ lọ lórí ilé méjìdínlógójì [38] àti Gbọ̀ngàn Ìjọba méjì tó ṣẹ́ kù, a ní in lọ́kàn pé kó parí títí ìparí oṣù April 2017.”

Àwọn ilé tí wọ́n tún kọ́ rèé. Tí wọ́n bá ti ṣe ògiri ilé kan sílẹ̀, tí wọ́n sì de òrùlé látilẹ̀, wọ́n á kàn gbé e nà ró ni. Wọ́n lè fi ọjọ́ mẹ́fà kọ́ ilé kan tán.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń bójú tó iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé, títí kan ṣíṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù, ohun táwọn èèyàn fi ṣètọrẹ ni wọ́n sì ń lò. Nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ kárí ayé, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé mẹ́sàn-án [209,000] ló wà lórílẹ̀-èdè Philippines.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Philippines: Dean Jacek, +63-2-224-4444