Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

MARCH 30, 2017
PERU

Peru: Omíyalé Ò Dáwọ́ Dúró, Yẹ̀pẹ̀ sì Ń Ya

Peru: Omíyalé Ò Dáwọ́ Dúró, Yẹ̀pẹ̀ sì Ń Ya

Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá ti mú kí omi yalé, kí yẹ̀pẹ̀ sì ya ní àgbègbè mẹ́rìnlélógún [24] nínú àgbègbè mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tó wà lórílẹ̀-èdè Peru, ìròyìn tá a sì ń gbọ́ ni pé kò tíì lè dáwọ́ dúró. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé lóṣù December sí March, tó jẹ́ àsìkò òjò ní orílẹ̀-èdè Peru, òjò ti rọ̀ ní ìlọ́po mẹ́wàá ju bó ṣe máa ń rọ̀ lọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ran àwọn ará wọn tó wà níbẹ̀ lọ́wọ́, títí kan àwọn míì tí àjálù náà ṣẹlẹ̀ sí.

Ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ọgbọ̀n [530] ni omi ti bà jẹ́, títí kan mẹ́fà nínú ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn (ìyẹn, Gbọ̀ngàn Ìjọba). Ìròyìn tó dé etí wa ni pé nílùú Huarmey, tó wà ní igba ó lé méjìdínláàádọ́rùn-ún [288] kìlómítà sílùú Lima, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí omi yalé wọn ló ti sá lọ sórí òrùlé ilé wọn, omi ò sì jẹ́ kí wọ́n lè sọ̀ kalẹ̀.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Peru ti ṣètò ìgbìmọ̀ mẹ́jọ tó ń ṣèrànwọ́ lásìkò àjálù láti bójú tó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbi tí àjálù náà ti wáyé, títí kan àgbègbè méjìlá [12] tí ìjọba ti kéde pé wọ́n nílò àbójútó pàjáwìrì. Àwọn ìgbìmọ̀ náà ti kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ ránṣẹ́, wọ́n sì ti gbé ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] gálọ́ọ̀nù omi lọ fún àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Láwọn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀, wọ́n ṣì máa kó oúnjẹ ránṣẹ́, tó ju ìlọ́po méjì èyí tí wọ́n kọ́kọ́ kó ránṣẹ́, wọ́n á sì gbé ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [2,400] gálọ́ọ̀nù omi ránṣẹ́. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Peru ló ti yọ̀ǹda ara wọn láti tún àwọn ibi tí omi bà jẹ́ ṣe.

Láti oríléeṣẹ́ wa ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá, wọ́n ń lo owó tí àwọn èèyàn fi ń ti iṣẹ́ ìwàásù táwa Ẹlẹ́rìí ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Peru: Norman R. Cripps, +51-1-708-9000