Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

DECEMBER 2, 2016
PANAMA

Ìjì Líle Tó Ṣọṣẹ́ Gan-an Wáyé ní Central America

Ìjì Líle Tó Ṣọṣẹ́ Gan-an Wáyé ní Central America

Ní November 23, 2016, ìjì líle tí wọ́n pè ní Hurricane Otto jà, ó rọ òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá, omi yalé, ó sì mú kí yẹ̀pẹ̀ àti òkè ya lulẹ̀ lórílẹ̀-èdè Costa Rica, Nikarágúà àti Panama, débi pé ó ba nǹkan jẹ́ gan-an. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn kó kúrò nílùú. Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ ni pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ò kú, wọn ò sì fara pa lórílẹ̀-èdè Costa Rica àti Nikarágúà. Àmọ́ ó bani nínú jẹ́ pé, lórílẹ̀-èdè Panama, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan fara pa, tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì kú nígbà tí òkè ya. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣètò bí wọ́n ṣe máa fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí nínú, kí wọ́n sì pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò fún wọn.

Láti oríléeṣẹ́ wa ní New York ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bójú tó ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ni wọ́n máa fún àwọn ìgbìmọ̀ tó ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù tó wà láwọn àgbègbè yẹn láṣẹ láti lò lára owó táwọn èèyàn fi ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-845-524-3000

Costa Rica: Pedro José Novoa Vargas, 506-8302-8499

Nikarágúà: Guillermo José Ponce Espinoza, 505-8856-1055

Panama: Dario Fernando De Souza, 507-6480-3770