Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

AUGUST 5, 2016
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ta Àwọn Ilé Tá À Ń Lò fún Oríléeṣẹ́ Wa ní Brooklyn

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ta Àwọn Ilé Tá À Ń Lò fún Oríléeṣẹ́ Wa ní Brooklyn

NEW YORK—Ní August 3, 2016, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ta àwọn ilé tá à ń lò fún oríléeṣẹ́ wa, tó wà ní 25/30 Columbia Heights nílùú Brooklyn, ní New York. Ìgbésẹ̀ pàtàkì lèyí jẹ́ fún wa bá a ṣe ń kó lọ sí oríléeṣẹ́ wa tuntun tá a kọ́ bá a ṣe fẹ́ nílùú Warwick, ní New York. Iléeṣẹ́ Kushner Companies àti LIVWRK la tà àwọn ilé tó wà ní Brooklyn yìí fún.

Àwọn ilé náà tóbi gan-an, àpapọ̀ wọn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó odindi àdúgbò méjì nínú ìlú. Àárín àgbègbè Brooklyn Heights, Fulton Ferry àti Dumbo ni àwọn ilé yìí wà, ibi tó bọ́ sí yìí sì dáa gan-an. A tún ta àwọn ilé mẹ́ta míì tá à ń lò mọ́ ilé 25/30 Columbia Heights, ìyẹn ilé 50 Columbia Heights, ilé 58 Columbia Heights àti ilé 55 Furman Street. Àwọn ilé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ti wà kí wọ́n tó kọ́ afárá Brooklyn Bridge tó wà ní tòsí ibẹ̀.

Ilé 50 Columbia Heights àti ilé 58 Columbia Heights

55 Furman Street

Iléeṣẹ́ oògùn tí wọ́n ń pè ní E.R. Squibb & Sons, tó wà lára àwọn iléeṣẹ́ tó di Bristol-Myers Squibb báyìí, ló ni ilé 25/30 Columbia Heights tẹ́lẹ̀. Àmì kan wà lórí òrùlé 30 Columbia Heights tí aago àti bí ojú ọjọ́ ṣe rí máa ń hàn lójú rẹ̀. Àìmọye ọdún làwọn èèyàn ti máa ń rí àmì yìí tí wọ́n bá ń wo àwọn ilé gogoro tó wà ní Brooklyn lọ́ọ̀ọ́kán, àtìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí sì ti ra ilé náà lọ́dún 1969 ni wọ́n ti yí ọ̀rọ̀ náà, “Squibb” tí wọ́n kọ sára àmì tó wà níbẹ̀ sí “Watchtower”. Ọ̀gbẹ́ni Richard Devine, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣàlàyé ohun tó mú wa ra àwọn ilé Brooklyn yìí nígbà yẹn, ó ní: “Nígbà yẹn, a nílò ibi tó fẹ́ tó lè gbà wá torí pé iṣẹ́ wa ti fẹjú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Àti pé a fẹ́ kí gbogbo ọ́fíìsì wa wà lójú kan, kì í ṣe bó ṣe wà kélekèle káàkiri ìlú Brooklyn.”

Ọ̀gbẹ́ni David A. Semonian, agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wa, sọ pé: “A ò lè gbàgbé ilé 25/30 Columbia Heights torí ó kó ipa pàtàkì nínú ìtàn wa, bẹ́ẹ̀ ni kò lè pa rẹ́ nínú ìtàn ìlú Brooklyn.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000