Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

OCTOBER 26, 2016
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fẹ́ Ta Ilé 97 Columbia Heights

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fẹ́ Ta Ilé 97 Columbia Heights

Ọ̀pọ̀ ọdún ni òtẹ́ẹ̀lì tó rẹwà tí wọ́n ń pè ní Hotel Margaret fi jẹ́ ilé tó ga jù ní Brooklyn.

ÌLÚ NEW YORK—Ní Wednesday, October 26, 2016, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kéde pé àwọn fẹ́ ta ilé àwọn tó wà ní 97 Columbia Heights ní Brooklyn, nílùú New York. Ilé gbígbé alájà mọ́kànlá [11] ni ilé yìí. Èèyàn á máa rí odò East River àti àwọn ilé gogoro Manhattan dáadáa láti ibẹ̀, ìkángun apá àríwá àdúgbò Brooklyn Heights tó rẹwà, tó sì jẹ́ ibi pàtàkì nínú ìtàn ìlú náà ni ilé yìí wà.

Wọ́n ṣe ilé 97 Columbia Heights kó rí bí wọ́n ṣe kọ́ òtẹ́ẹ̀lì tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀, bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi bàbà tẹ́ ara ilé náà, wọ́n fi amọ̀ pupa dárà sí ìta rẹ̀, àwọn fèrèsé rẹ̀ sì yọ igun lóríṣiríṣi.

Ibi tí òtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń pè ní Hotel Margaret tẹ́lẹ̀ wà ni ilé yìí wà. Iná ló jó òtẹ́ẹ̀lì náà lọ́dún 1980. Wọ́n wá gba Ọ̀gbẹ́ni Stanton Eckstut tó jẹ́ ayàwòrán ilé pé kó wá ya àwòrán ilé tuntun tí wọ́n á kọ́ síbẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni yìí yàwòrán ilé náà kó rí bí wọ́n ṣe kọ́ òtẹ́ẹ̀lì tó jóná yẹn, bí àpẹẹrẹ, wọ́n fi bàbà tẹ́ ara òtẹ́ẹ̀lì náà nígbà yẹn, wọ́n fi amọ̀ pupa dárà sí ìta rẹ̀, àwọn fèrèsé rẹ̀ sì yọ igun lóríṣiríṣi. Lọ́dún 1986, nígbà tí wọ́n ṣì ń kọ́ ilé tuntun yẹn lọ́wọ́, wọ́n tà á fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ibẹ̀ sì ni àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ wọn ń gbé. David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn sọ pé: “Àti ohun tó lé ní ọgbọ̀n [30] ọdún báyìí ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ti ń pe 97 Columbia Heights ní ilé wọn. Bí ilé yìí ṣe rẹwà, tó sì bọ́ síbi tó dáa yìí mú kó jẹ́ ilé to ṣàrà ọ̀tọ̀ fáwọn tó ń gbé ibẹ̀.”

Yàrá mẹ́tàdínlọ́gọ́rin [97] ló wà nínú ilé ńlá yìí, àwọn yàrá kan sì ní àgbàlá kékeré àti òrùlé téèyàn ti lè gbatẹ́gùn. Ilé náà tún ní ibi ìgbọ́kọ̀sí tó lè gba ọgbọ̀n [30] mọ́tò, ọ̀nà Orange Street sì ni àwọn tó ń gbébẹ̀ máa ń gbà wọlé.

Ọ̀gbẹ́ni Semonian sọ pé: “A ti ń kó kúrò lọ sí oríléeṣẹ́ wa ní Warwick, nílùú New York, a sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níbẹ̀ láti September 1, 2016. Ilé 97 Columbia Heights tá a fẹ́ tà yìí ni ìgbésẹ̀ tó kàn tá a fẹ́ gbé bá a ṣe ń kó lọ.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000