Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

DECEMBER 20, 2016
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ta Ilẹ̀ Tó Wà ní 85 Jay Street, Ọ̀kan Lára Àwọn Ilẹ̀ Tó Tóbi Jù ní Brooklyn

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ta Ilẹ̀ Tó Wà ní 85 Jay Street, Ọ̀kan Lára Àwọn Ilẹ̀ Tó Tóbi Jù ní Brooklyn

Ní Tuesday, December 20, 2016, àwa Ẹlẹ́rìí ta ilẹ̀ tó wà ní 85 Jay Street fún iléeṣẹ́ Kushner Companies, CIM Group, àti iléeṣẹ LIVWRK tí wọ́n pawọ́ pọ̀ jọ rà á. Ilẹ̀ yìí gba odindi àyè ńlá kan tó máa gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ní àdúgbò Dumbo tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ní Brooklyn, ó tó éékà mẹ́tàlélógún [23], àwọn tó bá rà á sì láṣẹ láti fi ibẹ̀ ṣe onírúurú iṣẹ́.

Láàárín ọdún 1986 sí nǹkan bí ọdún 1994, ọ̀pọ̀ àwókù ilé ló wà lórí ilẹ̀ yìí. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ra ilẹ̀ náà, ohun tí wọ́n ní lọ́kàn ni pé kí wọ́n kọ́lé sórí ilẹ̀ yẹn kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ ìtẹ̀wé wọn tó ti fẹjú sí i níbẹ̀. Àmọ́ àwọn Ẹlẹrìí pèrò dà, wọ́n pinnu pé àwọn máa kó ẹ̀ka iléeṣẹ́ wọn tó ń tẹ̀wé, tó ń dì í, tó sì ń kó o ránṣẹ́ kúrò ní Brooklyn lọ sí ilé wọn míì tó wà ní Wallkill, ní ìpínlẹ̀ New York. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, a ti kó oríléeṣẹ́ wa kúrò ní Brooklyn lọ sí Warwick, ní ìpínlẹ̀ New York. Ó sì ti ṣe díẹ̀ tá a ti ń ta àwọn ilé àti ilẹ̀ wa ní àdúgbò Brooklyn Heights àti Dumbo.

Richard Devine tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Irú ilẹ̀ tó wà ní 85 Jay Street yìí ṣọ̀wọ́n, ẹ̀ẹ̀kàn lọ́gbọ̀n lèèyàn lè rí irú ẹ̀, pàápàá torí bó ṣe tóbi tó, ibi tó wà àti bó ṣe máa wúlò tó lọ́jọ́ iwájú.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000