Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

DECEMBER 2, 2016
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ta Ilé 69 Adams

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ta Ilé 69 Adams

Ní November 29, 2016, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ta ilé wa tó wà ní 69 Adams Street, ní Brooklyn, nílùú New York. Ilé yìí fẹ̀, ó sì tóbi. Etí omi ló wà lágbègbè Dumbo, láàárín afárá Brooklyn àti Manhattan.

Ọdún 1994 làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ilé alájà mẹ́rin yìí, ibẹ̀ ni wọ́n máa ń gbọ́kọ̀ sí, tí wọ́n sì ti máa ń ṣe eré ìdárayá. Ilé yìí gba ọkọ̀ mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84], ẹ̀rọ méjì ló sì wà níbẹ̀ tó máa ń gbé ọkọ̀ lọ sí àjà òkè.

Richard Devine, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ pé: “Ilé tó wà ní 69 Adams yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an, kì í ṣe torí pé ó bọ́ síbi tó dáa nìkan ni, ó tún ní àyè tó fẹ̀. Òfin ilé kíkọ́ ládùúgbò yìí sì fọwọ́ sí i pé tí wọ́n bá fẹ́ kọ́ ilé yìí kó ga sí i, wọ́n ṣì lè sọ ọ́ di alájà méjìlá [12] tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Níbi tí ilẹ̀ ibẹ̀ sì fẹ̀ dé, wọ́n tún lè kọ́ irú ilé yẹn míì síbẹ̀.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-845-524-3000