Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

FEBRUARY 27, 2015
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Àmì Ẹ̀yẹ Pàtàkì Torí Wọn Ò Ṣe Ohun Tó Ń Ba Àyíká Jẹ́ Níbi Ilé tí Wọ́n Kọ́

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Àmì Ẹ̀yẹ Pàtàkì Torí Wọn Ò Ṣe Ohun Tó Ń Ba Àyíká Jẹ́ Níbi Ilé tí Wọ́n Kọ́

ÌLÚ NEW YORK—Àwọn èèyàn mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ń ṣe kárí ayé, àmọ́ wọ́n tún ti ń mọ̀ wọ́n mọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ń ṣe, tí wọn kì í tí ṣe ohun tó máa ba àyíká jẹ́.

Ilé tuntun méjì tí àwọn Ẹlẹ́rìí kọ́ sí Wallkill, nílùú New York, tó jẹ́ ti ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gba àmì ẹ̀yẹ látọ̀dọ̀ iléeṣẹ́ Green Building Initiative (tí wọ́n ń pè ní GBI). Àwọn ilé náà ni: Ilé Gbígbé F tó wà ní Watchtower Farms, tí wọ́n kọ́ parí ní òpin ọdún 2012, àti ilé táwọn Ọ́fíìsì iléeṣẹ́ Watchtower wà ní Wallkill, tí wọ́n kọ́ parí lọ́dún 2014. Ilé méjèèjì ló gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin, àmì ẹ̀yẹ tó sì ga jù nìyẹn.

Ilé táwọn Ọ́fíìsì Iléeṣẹ́ Watchtower wà

Shaina Sullivan, tó jẹ́ Olùdarí Ètò Káràkátà ní iléeṣẹ́ GBI sọ pé: “Kárí ayé, tá a bá kó ọgọ́rùn-ún [100] ilé tí iléeṣẹ́ wa ti yẹ̀ wò jọ, ilé tó gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin nínú wọn ò tó mẹ́rin.” Ìyáàfin Sullivan fi kún un pé ilé táwọn Ọ́fíìsì iléeṣẹ́ Watchtower wà ní Wallkill “ni ilé àkọ́kọ́ tí kì í ṣe ilé gbígbé tó máa gba àmì ẹ̀yẹ yìí.” Jenna Middaugh tó jẹ́ Olùdarí Iṣẹ́ Ìkọ́lé ní iléeṣẹ́ GBI, sọ pé: “Nínú ilé mẹ́tàlélógún [tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà] tó ti gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes mẹ́rin látọdún 2006, ilé táwọn Ọ́fíìsì iléeṣẹ́ Watchtower wà ní Wallkill ló gba máàkì tó pọ̀ jù.”

Ilé Gbígbé F ní Watchtower Farms

Àmì ẹ̀yẹ Green Globes máa ń mówó wọlé fún iléeṣẹ́ GBI, kí wọ́n sì tó lè fún ilé kan ní àmì ẹ̀yẹ yìí, wọ́n máa lọ wo ilé náà bóyá wọn ò ṣe ohun tó ń pa àyíká lára níbẹ̀, wọ́n á wá rán àwọn míì lọ wò ó káwọn náà lè jẹ́rìí sí i. Ilé tó máa gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí wọn ò ṣe ohun tó ń ba àyíká jẹ́ níbẹ̀, ní ti pé wọn ò ní máa fi omi ṣòfò níbẹ̀ lọ́nàkọnà, wọ́n á máa ṣọ́ iná lò, wọ́n á máa yẹra fún àwọn ohun táá máa tú èéfín sínú afẹ́fẹ́, wọ́n á máa lo àwọn ohun tí kò ní máa ba àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ jẹ́, wọn ò sì ní jẹ́ kí ohun tó máa ṣàkóbá fún ìlera wà nínú ilé náà.

Àwọn ohun èlò yìí máa ń fa agbára oòrùn, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti ń fa ìdá mẹ́wàá iná tí wọ́n ń lò ní ilé táwọn Ọ́fíìsì iléeṣẹ́ Watchtower wà. Ara ohun tó mú kí ilé náà gba àmì ẹ̀yẹ nìyẹn.

David Bean, tó ń bójú tó àwọn ilé tó jẹ́ ti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ohun tó ń lọ láyìíká ibẹ̀ sọ pé: “Àwọn àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n fún wa yìí jẹ́rìí sí i pé iṣẹ́ tó péye, tó sì pójú owó la máa ń fẹ́ ṣe ní gbogbo ilé wa tá à ń kọ́. A tún fẹ́ kí oríléeṣẹ́ wa tuntun tá à ń kọ́ sí Warwick, nílùú New York náà gba àmì ẹ̀yẹ Green Globes.

Wọ́n ń gbin koríko sórí òrùlé yìí, ó wà lára ohun tó fi hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí ò fẹ́ ṣohun tó máa ba àyíká jẹ́ ní oríléeṣẹ́ wọn tuntun ní Warwick, nílùú New York.

Zeny St. Jean, tó ń darí iṣẹ́ ìkọ́lé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe kárí ayé láti oríléeṣẹ́ wọn sọ pé: “Bá a ṣe túbọ̀ máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló jẹ wá lógún jù, àmọ́ àwọn àmì ẹ̀yẹ tá a rí gbà yìí múnú wa dùn torí ó fi hàn pé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ náà rí i pé à ń gbìyànjú láti má ṣe ohun tó máa pa àyíká lára ní àwọn ilé tá à ń kọ́ kárí ayé, ẹ̀rí ọkàn wa ni ò sì jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000