Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

MAY 22, 2017
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwọn Aráàlú Sọ Ohun Tó Dáa Nípa Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nígbà Tí Wọ́n Wá Wo Oríléeṣẹ́ Wa Tuntun

Àwọn Aráàlú Sọ Ohun Tó Dáa Nípa Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nígbà Tí Wọ́n Wá Wo Oríléeṣẹ́ Wa Tuntun

NEW YORK—Ní Saturday, April 29, 2017, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣí oríléeṣẹ́ wọn tuntun tó wà nílùú Warwick ní New York sílẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì káwọn èèyàn lè wá wò ó, àwọn tó sì wá lọ́tẹ̀ yìí pọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.

Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé méjìdínláàádọ́rin [468] làwọn tó wá síbẹ̀ ní Saturday tó kọjá yìí, mẹ́tàléláàádọ́rin [73] ló fi lé sí iye àwọn tó wá ní Saturday tó kọjá. Troy Snyder, tó jẹ́ alábòójútó ilé náà sọ pé, “Inú wa dùn gan-an pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn aládùúgbò wa, pàápàá àwọn aláṣẹ ìlú, ló wá wo oríléeṣẹ́ wa. Àwọn kan wà lára àwọn aráàlú yẹn tó tún wá lẹ́ẹ̀kejì yìí, torí ohun tí wọ́n rí lọ́sẹ̀ tó kọjá tí wọ́n kọ́kọ́ wá àti bá a ṣe ṣe sí wọn nígbà tí wọ́n wá.”

Ọjọ́ Saturday méjì tó tẹ̀ léra làwọn Ẹlẹ́rìí ṣí oríléeṣẹ́ wọn sílẹ̀ káwọn èèyàn lè wá wò ó, ní aago mẹ́wàá àárọ̀ sí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́, àròpọ̀ iye àwọn tó wá sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́tàlélọ́gọ́ta [863]. Ọ̀gbẹ́ni Snyder sọ pé, “Àṣeyọrí ńlá ló tìdí ohun tá a ṣe yìí yọ. Ọ̀pọ̀ ohun rere làwọn tó wá síbẹ̀ sọ. A sì ń retí ìgbà míì tá a tún máa gba àwọn aládùúgbò wa lálejò tí wọ́n bá fẹ́ wá wo oríléeṣẹ́ wa, kí wọ́n rìn yí ká ọgbà wa, kí wọ́n sì wo ibi tá a kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí.”

Ingrid Magar

Ingrid Magar, tó ń gbé ní ọgbà Tuxedo Park ní New York, tí kò jìnnà sí oríléeṣẹ́ náà, wà lára ọ̀pọ̀ àwọn aládùúgbò tó wá síbẹ̀. Ọdún méjìdínlógún [18] ló fi bá iléeṣẹ́ International Nickel Company ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tí wọ́n ti ń ṣàyẹ̀wò, tí wọ́n sì ti ń ṣèwádìí. Iléeṣẹ́ yẹn ló wà níbi tí oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí wà tẹ́lẹ̀. Obìnrin yìí rántí bí wọ́n ṣe ń lo ibẹ̀ nígbà yẹn, ó ní: “Inú mi dùn sí ohun tí ibí yìí dà. Ó pẹ́ gan-an tí kò fi sí ẹni tó ń lo ibẹ̀, a wá ń rò ó pé, ‘Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí ibí yìí.’ Ibí yìí rẹwà gan-an, ẹ sì ti wá bù kún ẹwà ẹ̀.” Ms. Magar tún sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó kọ́lé sórí ilẹ̀ náà báyìí, ó ní: “Lójú tèmi, aládùúgbò rere lẹ̀yin [Ẹlẹ́rìí Jèhófà]. Ẹ lójú àánú, ẹ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, ọ̀rọ̀ àyíká àti ọ̀rọ̀ ìlú sì jẹ yín lógún, ẹ wò ó, inú wa dùn gan-an pé ẹ kó wá sí àdúgbò wa.”

William Hoppe

William Hoppe, ẹnjiníà tí Ìlú Warwick rán wá ṣe àyẹ̀wò oríléeṣẹ́ náà ní ọdún méjì tí wọ́n lò gbẹ̀yìn láti fi kọ́ ọ, sọ pé: “Ó ṣe kedere pé iṣẹ́ tó dáa jù lọ ni wọ́n fẹ́ ṣe síbẹ̀.  . . . Ó hàn nínú bí wọ́n ṣe kọ́ ilé náà, iṣẹ́ gidi ni wọ́n ṣe síbẹ̀. Ohun míì tó tún wú mi lórí gan-an lásìkò tí iṣẹ́ yẹn ń lọ lọ́wọ́ ni bí wọ́n ṣe ro ti àwọn ẹranko, igi àtàwọn ohun tó wà ní àyíká mọ́ ilé tí wọ́n kọ́ yìí, bí wọ́n tún ṣe ń bójú tó o, tí wọn ò sì pa àyíká lára jálẹ̀ àsìkò tí wọ́n fi kọ́ ilé náà wú mi lórí. Àpẹẹrẹ pàtàkì ló jẹ́ fáwọn míì tó bá fẹ́ ṣiṣẹ́ ìkọ́lé.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000