Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

DECEMBER 7, 2015
ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ

Àwa Ẹlẹ́rìí Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ta Àwọn Ilé àti Ilẹ̀ Wa Tó Wà ní Brooklyn

Àwa Ẹlẹ́rìí Ti Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ta Àwọn Ilé àti Ilẹ̀ Wa Tó Wà ní Brooklyn

ÌLÚ NEW YORK—Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ta àwọn ilé àti ilẹ̀ wa kan nílùú Dumbo àti Brooklyn Heights ní Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York. Wìtìwìtì láwọn èèyàn ń du àti rà á. A fẹ́ ta ilẹ̀ wa kan tó wà ní 85 Jay Street, ilẹ̀ yìí wà lára àwọn ilẹ̀ tá ò tíì kọ́lé sí tó fẹ̀ jù nílùú Brooklyn. A tún fẹ́ ta ilé alájà mẹ́wàá kan tó wà ní 124 Columbia Heights. Bákan náà a tún fẹ́ ta orílé-iṣẹ́ tá à ń lò báyìí, èyí tó wà ní 25/30 Columbia Heights. Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la fẹ́ ta àwọn dúkìá yìí, a sì ti ṣètò pé kí Watchtower Real Estate Office bá wa tà á.

Richard Devine, tó jẹ́ agbẹnusọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ nípa ilẹ̀ tó fẹ̀ gan-an tá a sọ pé ó wà ní 85 Jay Street yẹn pé: “Ilẹ̀ yìí fẹ̀ dé àwọn odi ìlú tó wà lágbègbè ìlú Dumbo ó sì wà ní ipò to dáa.”

Ilẹ̀ tó wà ní 85 Jay Street wà ní ìsàlẹ̀ afárá Manhattan ní tòsí ìlú Dumbo.

Ibì kan táwọn èèyàn máa ń ṣeré lọ ní àgbègbè Brooklyn Heights Historic District tọ́pọ̀ èèyàn fẹ́ràn ni ilé alájà mẹ́wàá tó wà ní 124 Columbia Heights wà. Ọ̀gbẹ́ni Devine sọ pé: “Ilé àwòṣífìlà ni. Téèyàn bá wà nínú ilé yìí, á máa rí àwọn ohun tó rẹwà bí afárá Brooklyn, ère tí wọ́n fi ń dá ìlú New York mọ̀, àtàwọn ilé gíga Lower Manhattan.”

Ilé tó wà ní 124 Columbia Heights wà ní àdúgbò Brooklyn Heights.

Ọjọ́ ti pẹ́ tí oríléeṣẹ́ wa ti wà ní 25/30 Columbia Heights, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé nílùú New York sì ti mọ̀ ọ́n mọ́ àmì Ilé ìṣọ́ àti aago tó wà níbẹ̀. Pẹ̀lú bí ilé yìí ṣe ga tó, to sì fẹ̀ gan-an, síbẹ̀ kò dí èèyàn lọ́wọ́ láti rí afára Brooklyn lọ́ọ̀ọ́kán.

Ọ̀gbẹ́ni Devine tún sọ pé, “Bá a ṣe ń ta àwọn dúkìá yìí, ohun tó kàn ni ká kó lọ sí oríléeṣẹ́ wa tó wà ní Warwick nílùú New York.”

Láti mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ilé àti ilẹ̀ tá a fẹ́ tà yìí, jọ̀ọ́ lọ sórí ìkànnì www.WatchtowerBrooklynRealEstate.com. Tó o bá fẹ́, o lè rí àwọn ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àtàwọn fọ́tò gbà látọwọ́ Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde,, tel. +1 718 560 5000