Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

NOVEMBER 15, 2016
NEW ZEALAND

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Le Gan-an Wáyé ní New Zealand, Ọ̀pọ̀ Irú Ẹ̀ Ló sì Wáyé Tẹ̀ Léra

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Le Gan-an Wáyé ní New Zealand, Ọ̀pọ̀ Irú Ẹ̀ Ló sì Wáyé Tẹ̀ Léra

Lóru ọjọ́ Monday, November 14, 2016, ìmìtìtì ilẹ̀ tó le gan-an wáyé ní erékùṣù South Island lórílẹ̀-èdè New Zealand. Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ ni pé èèyàn méjì ló kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ilẹ̀ tún mì tìtì lẹ́yìn ti àkọ́kọ́ yẹn, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ le tó ti àkọ́kọ́. Ọ̀pọ̀ ilé ló wó, ó ba iná àtàwọn wáyà fóònù jẹ́, ó sì ba ojú ọ̀nà tí mọ́tò àti ọkọ̀ ojú irin ń gbà jẹ́, ó tún ba ẹ̀rọ omi àtàwọn ọ̀pá tí omi ìdọ̀tí ń gbà jẹ́.

Ìròyìn tá a kọ́kọ́ gbọ́ lẹ́nu àwọn alàgbà ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè New Zealand àti ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni pé ìkankan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí ò ṣèṣe, ìkankan ò sì kú. Àwọn Ẹlẹ́rìí ti ṣètò ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù sílùú Christchurch, tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91] sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn ibi tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà ti rinlẹ̀ jù. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ibi ìjọsìn wọn ò fi bẹ́ẹ̀ bà jẹ́, ìgbìmọ̀ náà ń sapá láti pèsè ohun táwọn tí àjálù dé bá nílò, wọ́n sì ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wọ́n nínú.

Láti oríléeṣẹ́ wa ni New York ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń bójú tó ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn ló máa ń fún ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ yìí láṣẹ láti lo owó táwọn èèyàn fi ń ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Ọsirélíà àti New Zealand: Rodney Spinks, 61-2-9829-5600