Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

SEPTEMBER 20, 2017
MEXICO

Hurricane Max jà ní gúùsù orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

Hurricane Max jà ní gúùsù orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

Ní September 14, 2017, ìjì ńlá kan tí wọ́n pè ní Hurricane Max jà ní gúùsù etíkun Pàsífíìkì lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ó sì fa ìjì líle. Ìjì náà mú kí atẹ́gùn tó lágbára fẹ́, ó sì tún fa omíyalé tó ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́.

Ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ láti mọ bí ìjì náà ṣe ṣọṣẹ́ tó. Àmọ́, ó bani nínú jẹ́ láti gbọ́ pé ìjì náà pa ọ̀kan lára àwọn arákùrin wa níbi tó ti ń gbìyànjú láti ran aládùúgbò rẹ̀ kan lọ́wọ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà ní Mexico ṣètò ìrànwọ́, wọ́n sì ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìjọ àdúgbò láti pèsè ìrànwọ́ fún àwọn tí ìjì náà ṣe lọ́ṣẹ́.

Media Contacts:

International: David A. Semonian, Office of Public Information, +1-845-524-3000

Mexico: Gamaliel Camarillo, +52-555-133-3048