Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

MAY 22, 2015
MEXICO

Wọ́n Pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sí Ayẹyẹ Tó Fa Kíki Tàwọn Òǹṣèwé Nílùú Tó Ń Sọ Èdè Sípáníìṣì

Wọ́n Pe Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sí Ayẹyẹ Tó Fa Kíki Tàwọn Òǹṣèwé Nílùú Tó Ń Sọ Èdè Sípáníìṣì

LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ MEXICO—Wọn pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti wá kópa nínú ayẹyẹ àwọn òǹṣèwé ti ìlú Guadalajara, fún ìlú tó ń sọ èdè Sípáníìṣì, ayẹyẹ yìí ló tíì fa kíki jùlọ lágbàáyé, òun sì ló ṣèkejì ayẹyẹ ìwé Frankfurt tó lárinrin jù lágbàáyé, èyí tí wọ́n ṣe ni ìlú Jámánì. Ìlú Guadalajara lórílẹ̀-èdè Mexiconi wọ́n ti ṣe ayẹyẹ náà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ ní November 29 sí December 7, 2014, àwọn èèyàn tó lé ní ọ̀kẹ́ méjìdínlógójì [760,000] ló pésẹ̀ síbẹ̀.

Àwọn èèyàn gba ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ tí apá kìíní àti apá kejì.

Àwọn ilé iṣẹ́ tí iye wọ́n jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] ló wá láti ìlú mẹ́rìnlélógójì [44] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ṣe àtíbàbà tí wọ́n kó Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tó dá lórí Bíbélì sí, wọ́n tún kó àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa bí ìdílé ṣe lè láyọ̀ síbẹ̀, ìwé to sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn ọmọ.

Gamaliel Camarillo, tó jẹ́ agbẹnusọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Mexico so pé, “Ní gbogbo ọjọ́ mẹ́rin tá a fi wà nídìí àtíbàbà yìí, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] ló wá sọ́dọ̀ wa, tí wọ́n sì gba ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [29,000] ìwé lọ́fẹ̀ẹ́. Àmọ́ a ò fẹ́ dá a dúró sí pé wọ́n kàn gbàwé, torí àwọn ìtẹ̀jáde wa dá lórí ìmọ̀ràn Bíbélì nípa bá a ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dáa, tó sì lè ṣe ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn láǹfààní lójoojúmọ́ .”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tẹlifóònù +1 718 560 5000

Mexico: Gamaliel Camarillo, tel. +52 555 133 3048