Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

NOVEMBER 4, 2015
MEXICO

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Àmì Ẹ̀yẹ Nítorí Iṣẹ́ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí À Ń Ṣe Láwọn Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Àmì Ẹ̀yẹ Nítorí Iṣẹ́ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí À Ń Ṣe Láwọn Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

ÌLÚ MẸ́SÍKÒ—Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tó wà ní ìpínlẹ̀ Baja California ní Mẹ́síkò fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àmì ẹ̀yẹ torí pé wọ́n mọrírì iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń ṣe láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n wọn. Daniel De La Rosa Anaya tó jẹ́ akọ̀wé ọ̀ràn ààbò ìpínlẹ̀ náà àti Jesús Héctor Grijalva Tapia tó jẹ́ akọ̀wé ọgbà ẹ̀wọ̀n ìpínlẹ̀ náà ló fọwọ́ sí ìwé àmì ẹ̀yẹ yìí.

Ìwé àmì ẹ̀yẹ náà kà pé: “Akọ̀wé ọ̀ràn ààbò tó ń ṣojú fún ìjọba ìpínlẹ̀ gbóríyìn fún ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a sì mọrírì iṣẹ́ takuntakun tí ẹ̀ ń ṣe àti bẹ́ ẹ ṣe ń kọ́wọ́ ti ìjọba ní ìpínlẹ̀ Baja California; a mọyì bẹ́ẹ ṣe ran àwọn ẹlẹ́wọn wa lọ́wọ́ láti mú kí wọ́n túbọ̀ wúlò láwùjọ kí ìgbésí ayé wọn sì túbọ̀ nítumọ̀.”

Jesús Manuel López Moreno, olùdarí Ibi Ìmúpadàbọ̀sípò Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣèbẹ̀wò lóòrèkóòrè sáwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní ìpínlẹ̀ Baja California, títí kan ọgbà ẹ̀wọ̀n kan nílùú Mexicali tó jẹ́ olú-ìlú Baja California. Láti ọdún 1991 tí ẹlẹ́wọ̀n kan ti ké sí wọn ni wọ́n ti ń ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Nígbà tí Jesús Manuel López Moreno tó jẹ́ olùdarí Ibi Ìmúpadàbọ̀sípò Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà ń fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sọ pé: “Bẹ́ẹ ṣe ń wá síbí, tẹ́ ẹ sì ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ [àwọn ẹlẹ́wọ̀n] yìí jẹ yín lógún ló ń mú ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ káwọn náà lè fẹnu ara wọn sọ pé: ‘Èèyàn làwa náà. Ìgbésí ayé wa sì nítumọ̀ torí pé a mọ̀ pé tí àkókò bá tó, àwa náà á pa dà sáàárín àwọn èèyàn, a sì máa wúlò láwùjọ.’ . . . Mo mọ rírì ìrànlọ́wọ́ tẹ́ ẹ̀ ń ṣe. Mo dúpẹ́, mo tọ́pẹ́ dá.”

Gamaliel Camarillo tó jẹ́ aṣojú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Lájorí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, tó fi mọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n, kí wọ́n lè lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Ìjọ kan tó wà ní ìlú Mexicali tiẹ̀ ròyìn pé ó kéré tán, àwọn mẹ́jọ ló ti ṣèrìbọmi nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Mexicali. A gbà gbọ́ pé gbogbo èèyàn pátá ló yẹ kó jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ Bíbélì.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000

Mexico: Gamaliel Camarillo, tel. +52 555 133 3048