Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

JUNE 13, 2017
MALAWI

Àwọn Ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà Méjì tí Àwọn Aláṣẹ Lé Kúrò Níléèwé Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀rí Ọkàn Ti Pa Dà Síléèwé

Àwọn Ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà Méjì tí Àwọn Aláṣẹ Lé Kúrò Níléèwé Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀rí Ọkàn Ti Pa Dà Síléèwé

ÌLÚ LILONGWE, lórílẹ̀-èdè Màláwì—Ní May 3, 2017, àwọn aláṣẹ gbà kí Aaron Mankhamba, ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] àti Hastings Mtambalika, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15], pa dà sí iléèwé alákọ̀ọ́kọ́-bẹ̀rẹ̀ Khombe Primary School tí wọ́n ń lọ. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ọmọ méjèèjì, torí pé wọ́n kọ̀ láti kọ orin orílẹ̀-èdè ni wọ́n sì ṣe lé wọn kúrò níléèwé tẹ́lẹ̀. Láti February 13, 2017 ni wọn ò ti jẹ́ káwọn ọmọ méjèèjì wọ kíláàsì mọ́. Àwọn òbí àwọn ọmọ náà àtàwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá lọ yọjú sí àwọn aláṣẹ iléèwé náà, kó tó di pé wọ́n gbà kí àwọn ọmọ náà pa dà síléèwé.

Nígbà táwọn aṣojú láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá àwọn aláṣẹ iléèwé náà sọ̀rọ̀, wọ́n fi lẹ́tà méjì hàn wọ́n látọ̀dọ̀ ìjọba orílẹ̀-èdè Màláwì, ìyẹn sì ṣèrànwọ́ gan-an. Ọdún 1997 ni wọ́n kọ ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Màláwì sì ni ìjọba dìídì kọ ọ́ sí. Wọ́n sọ nínú lẹ́tà náà pé wọ́n gba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè láti má ṣe kọ orin orílẹ̀-èdè. Ọdún 2017 ni wọ́n kọ lẹ́tà kejì, wọ́n rọ àwọn aláṣẹ iléèwé pé kí wọ́n má fi òmìnira ẹ̀sìn tí àwọn ọmọ iléèwé ní dù wọ́n.

Hastings sọ pé àsìkò tó ṣe pàtàkì gan-an níléèwé ni wọ́n pe àwọn pa dà yìí. Ìdí ni pé ìdánwò tí ìjọba máa ń ṣe fún wọn ti sún mọ́lé lásìkò yẹn. Hastings sọ pé: “Ọkàn wa ò balẹ̀ rárá, a ti ń wò ó pé a ò ní bá àwọn tó kù ṣe ìdánwò yẹn. Ẹ̀ẹ̀kan péré la sì máa ń láǹfààní láti ṣe irú ìdánwò yẹn lọ́dún.” Ká sọ pé àwọn ọmọ yìí ò ṣe ìdánwò yẹn ni, ṣe ni wọn ì bá tún kíláàsì tí wọ́n wà kà.

Augustine Semo, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Màláwì sọ pé: “Inú àwọn ọmọ iléèwé méjì yìí dùn pé àwọn aláṣẹ jẹ́ kí wọ́n ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbà láyè, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ iléèwé pé wọn ò fọwọ́ rọ́ òmìnira ẹ̀sìn táwọn ọmọ yìí ní sẹ́yìn, tí wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n pa dà síléèwé.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Màláwì: Augustine Semo, +265-1-762-111