Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

JULY 20, 2017
JAPAN

Òjò Àrọ̀ọ̀rọ̀dá Mú Kí Omi Yalé ní Kyushu, Lórílẹ̀-èdè Japan

Òjò Àrọ̀ọ̀rọ̀dá Mú Kí Omi Yalé ní Kyushu, Lórílẹ̀-èdè Japan

Lẹ́yìn tí ìjì líle tí wọ́n ń pè ní Typhoon Nanmadol jà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Japan, òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tí irú ẹ̀ ò rọ̀ rí rọ̀ ní Wednesday, July 5, 2017 ní Kyushu, erékùṣù tó tóbi ṣìkẹta lórílẹ̀-èdè náà. Èyí mú kí omi àti ẹrẹ̀ ya, ó sì mú kó di dandan fáwọn aláṣẹ láti sọ fáwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti ọgbọ̀n [430,000] tó ń gbé lágbègbè náà pé kí wọ́n kó kúrò níbẹ̀. Láàárín wákàtí méjìlá [12] tí òjò fi rọ̀, omi tó ń ṣàn fẹ́rẹ̀ẹ́ jìn tó ẹsẹ̀ bàtà méjì sílẹ̀. Ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ tó dé etí ìgbọ́ wa ni pé èèyàn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] ló ti kú. Ọ̀kan lára ibi tí àjálù náà ti rinlẹ̀ jù ni àgbègbè Fukuoka, ní àríwá erékùṣù Kyushu.

A ò gbọ́ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ṣèṣe tàbí fara pa yánnayànna, àmọ́ omi ba ilé ọ̀pọ̀ nínú wọn jẹ́. Àwọn ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò náà ń ṣèrànwọ́ fáwọn ará wọn, wọ́n ń pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Japan: Ichiki Matsunaga, +81-46-233-0005