Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

APRIL 29, 2016
JAPAN

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Japan

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Wáyé ní Japan

Ní April 14 àti April 16, 2016, ìmìtìtì ilẹ̀ méjì tó lágbára wáyé ní erékùṣù Kyushu lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Japan. Èyí tó kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ lágbára díẹ̀, àmọ́ ìkejì le jù ú lọ. Àìmọye ìgbà lẹ́yìn ìyẹn ni ilẹ̀ tún ti sẹ̀, àmọ́ kò le tó méjì àkọ́kọ́. Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní àádọ́rin (70) ló wà níbi tí ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, àmọ́ Ẹlẹ́rìí kankan ò kú, bẹ́ẹ̀ ni ìkankan nínú wọn ò fara pa yánnayànna. Ilé wọn tó lé ní àádọ́rin (70) ló bà jẹ́ gan-an, mẹ́tàdínlógún (17) lára ilé wọn ló sì bà jẹ́ kọjá àtúnṣe. Torí pé ilẹ̀ ṣì ń sẹ̀ léraléra, wọ́n kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) kúrò ní ilé wọn lọ sí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn, ibẹ̀ ni wọ́n ń sùn, wọ́n sì ń fún wọn lóúnjẹ níbẹ̀. Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Japan ti ṣètò àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé láti pèsè ìrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000

Japan: Ichiki Matsunaga, tel. +81 46 233 0005